O. Daf 31:9-18

O. Daf 31:9-18 YBCV

Ṣãnu fun mi, Oluwa, nitori ti emi wà ninu iṣẹ́: oju mi fi ibinujẹ run, ọkàn mi ati inu mi. Emi fi ibinujẹ lò ọjọ mi, ati ọdun mi ti on ti imi-ẹ̀dun: agbara mi kú nitori ẹ̀ṣẹ mi, awọn egungun mi si run. Emi di ẹni-ẹ̀gan lãrin awọn ọta mi gbogbo, pẹlupẹlu lãrin awọn aladugbo mi, mo si di ẹ̀ru fun awọn ojulumọ mi: awọn ti o ri mi lode nyẹra fun mi. Emi ti di ẹni-igbagbe kuro ni ìye bi okú: emi dabi ohun-elo fifọ́. Nitori ti emi ti ngbọ́ ẹ̀gan ọ̀pọ enia: ẹ̀ru wà niha gbogbo: nigbati nwọn ngbimọ pọ̀ si mi, nwọn gbiro ati gbà ẹmi mi kuro. Ṣugbọn emi gbẹkẹle ọ, Oluwa: emi ni, Iwọ li Ọlọrun mi. Igba mi mbẹ li ọwọ rẹ: gbà mi li ọwọ awọn ọta mi, ati li ọwọ awọn ti nṣe inunibini si mi, Ṣe oju rẹ ki o mọlẹ si iranṣẹ rẹ lara: gbà mi nitori ãnu rẹ. Máṣe jẹ ki oju ki o tì mi, Oluwa; nitori ti emi nkepè ọ; enia buburu ni ki oju ki o tì, awọn ni ki a mu dakẹ ni isa-okú. Awọn ète eke ni ki a mu dakẹ; ti nsọ̀rọ ohun buburu ni igberaga ati li ẹ̀gan si awọn olododo.