O. Daf 31:9-18
O. Daf 31:9-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣãnu fun mi, Oluwa, nitori ti emi wà ninu iṣẹ́: oju mi fi ibinujẹ run, ọkàn mi ati inu mi. Emi fi ibinujẹ lò ọjọ mi, ati ọdun mi ti on ti imi-ẹ̀dun: agbara mi kú nitori ẹ̀ṣẹ mi, awọn egungun mi si run. Emi di ẹni-ẹ̀gan lãrin awọn ọta mi gbogbo, pẹlupẹlu lãrin awọn aladugbo mi, mo si di ẹ̀ru fun awọn ojulumọ mi: awọn ti o ri mi lode nyẹra fun mi. Emi ti di ẹni-igbagbe kuro ni ìye bi okú: emi dabi ohun-elo fifọ́. Nitori ti emi ti ngbọ́ ẹ̀gan ọ̀pọ enia: ẹ̀ru wà niha gbogbo: nigbati nwọn ngbimọ pọ̀ si mi, nwọn gbiro ati gbà ẹmi mi kuro. Ṣugbọn emi gbẹkẹle ọ, Oluwa: emi ni, Iwọ li Ọlọrun mi. Igba mi mbẹ li ọwọ rẹ: gbà mi li ọwọ awọn ọta mi, ati li ọwọ awọn ti nṣe inunibini si mi, Ṣe oju rẹ ki o mọlẹ si iranṣẹ rẹ lara: gbà mi nitori ãnu rẹ. Máṣe jẹ ki oju ki o tì mi, Oluwa; nitori ti emi nkepè ọ; enia buburu ni ki oju ki o tì, awọn ni ki a mu dakẹ ni isa-okú. Awọn ète eke ni ki a mu dakẹ; ti nsọ̀rọ ohun buburu ni igberaga ati li ẹ̀gan si awọn olododo.
O. Daf 31:9-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣàánú fún mi, ìwọ OLúWA, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú; ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn, ọkàn àti ara mi pẹ̀lú. Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn; agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi, egungun mi sì ti rún dànù. Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo, pẹ̀lúpẹ̀lú láàrín àwọn aládùúgbò mi, mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi; àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi. Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú; Èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́. Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká; tí wọn gbìmọ̀ pọ̀ sí mi, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi láti gba ẹ̀mí mi. Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ OLúWA Mo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.” Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ; gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi àti àwọn onínúnibíni. Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára; Gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin. Má ṣe jẹ́ kí ojú ki ó tì mí, OLúWA; nítorí pé mo ké pè ọ́; jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú; jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú. Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́, pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn, wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo.
O. Daf 31:9-18 Yoruba Bible (YCE)
Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí pé mo wà ninu ìṣòro. Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì; àárẹ̀ sì mú ọkàn ati ara mi. Nítorí pé ìbànújẹ́ ni mo fi ń lo ayé mi; ìmí ẹ̀dùn ni mo sì fi ń lo ọdún kan dé ekeji. Ìpọ́njú ti gba agbára mi; gbogbo egungun mi sì ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Ẹni ẹ̀gàn ni mí láàrin gbogbo àwọn ọ̀tá mi, àwòsọkún ni mí fún àwọn aládùúgbò. Mo di àkòtagìrì fún àwọn ojúlùmọ̀ mi, àwọn tí ó rí mi lóde sì ń sá fún mi. Mo di ẹni ìgbàgbé bí ẹni tí ó ti kú; mo dàbí àkúfọ́ ìkòkò. Mò ń gbọ́ tí ọ̀pọ̀ eniyan ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, bí wọ́n ti ń gbìmọ̀ pọ̀ nípa mi, tí wọ́n sì ń pète ati pa mí; wọ́n ń ṣẹ̀rù bà mí lọ́tùn-ún lósì. Ṣugbọn, mo gbẹ́kẹ̀lé ọ, OLUWA, Mo ní, “Ìwọ ni Ọlọrun mi.” Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ; gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, ati lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi. Jẹ́ kí èmi iranṣẹ rẹ rí ojurere rẹ, gbà mí là, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Má jẹ́ kí ojú tì mí, OLUWA, nítorí ìwọ ni mò ń ké pè. Jẹ́ kí ojú ti àwọn eniyan burúkú; jẹ́ kí ẹnu wọn wọ wòwò títí wọ ibojì. Jẹ́ kí àwọn òpùrọ́ yadi, àní àwọn tí ń fi ìgbéraga ati ẹ̀gàn sọ̀rọ̀ àìdára nípa olódodo.