Ìró ayọ̀ ati ti ìṣẹ́gun mbẹ ninu agọ awọn olododo; ọwọ ọtún Oluwa li a gbega: ọwọ ọtún Oluwa nṣe agbara. Ọwọ ọtún Oluwa li a gbega: ọwọ ọtún Oluwa nṣe agbara. Emi kì yio kú, bikoṣe yiyè, ki emi ki o si ma rohin iṣẹ Oluwa. Oluwa nà mi gidigidi: ṣugbọn kò fi mi fun ikú. Ṣi ilẹkun ẹnu-ọ̀na ododo silẹ fun mi: emi o ba ibẹ wọle, emi o ma yìn Oluwa. Eyi li ẹnu-ọ̀na Oluwa, ti awọn olododo yio ba wọle. Emi o yìn ọ: nitori ti iwọ gbohùn mi, iwọ si di igbala mi. Okuta ti awọn ọ̀mọle kọ̀ silẹ li o di pataki igun ile. Lati ọdọ Oluwa li eyi: o ṣe iyanu li oju wa. Eyi li ọjọ ti Oluwa da: awa o ma yọ̀, inu wa yio si ma dùn ninu rẹ̀. Ṣe igbala nisisiyi, emi mbẹ ọ, Oluwa: Oluwa emi bẹ ọ, rán alafia. Olubukún li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa: awa ti fi ibukún fun ọ lati ile Oluwa wá. Ọlọrun li Oluwa, ti o ti fi imọlẹ hàn fun wa: ẹ fi okùn di ẹbọ na mọ́ iwo pẹpẹ na. Iwọ li Ọlọrun mi, emi o si ma yìn ọ, iwọ li Ọlọrun mi, emi o mã gbé ọ ga. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa; nitori ti o ṣeun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
Kà O. Daf 118
Feti si O. Daf 118
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 118:15-29
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò