O. Daf 116

116
Orin Ọpẹ́
1EMI fẹ Oluwa nitori ti o gbọ́ ohùn mi ati ẹ̀bẹ mi.
2Nitori ti o dẹ eti rẹ̀ si mi, nitorina li emi o ma kepè e niwọn ọjọ mi.
3Ikẹkùn ikú yi mi ka, ati irora isà-òkú di mi mu; mo ri iyọnu ati ikãnu.
4Nigbana ni mo kepè orukọ Oluwa; Oluwa, emi bẹ̀ ọ, gbà ọkàn mi.
5Olore-ọfẹ li Oluwa, ati olododo; nitõtọ, alãnu li Ọlọrun wa.
6Oluwa pa awọn alaimọ̀kan mọ́: a rẹ̀ mi silẹ tan, o si ràn mi lọwọ.
7Pada si ibi isimi rẹ, iwọ ọkàn mi; nitori ti Oluwa ṣe é lọ́pọlọpọ fun ọ.
8Nitori ti iwọ gbà ọkàn mi lọwọ ikú, oju mi lọwọ omije, ati ẹsẹ mi lọwọ iṣubu.
9Emi o ma rìn niwaju Oluwa ni ilẹ alãye.
10Emi gbagbọ́, nitorina li emi ṣe sọ: mo ri ipọnju gidigidi.
11Mo wi ni iyara mi pe: Eke ni gbogbo enia.
12Kili emi o san fun Oluwa nitori gbogbo ore rẹ̀ si mi?
13Emi o mu ago igbala, emi o si ma kepè orukọ Oluwa.
14Emi o san ileri ifẹ mi fun Oluwa, nitõtọ li oju gbogbo awọn enia rẹ̀.
15Iyebiye ni ikú awọn ayanfẹ rẹ̀ li oju Oluwa.
16Oluwa nitõtọ iranṣẹ rẹ li emi; iranṣẹ rẹ̀ li emi, ati ọmọ iranṣẹ-birin rẹ: iwọ ti tú ìde mi.
17Emi o ru ẹbọ ọpẹ si ọ, emi o ma ke pè orukọ Oluwa.
18Emi o san ileri ifẹ mi fun Oluwa, nitõtọ li oju gbogbo awọn enia rẹ̀.
19Ninu àgbala ile Oluwa, li arin rẹ, iwọ Jerusalemu. Ẹ yìn Oluwa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 116: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀