O. Daf 113

113
Yíyin OLUWA fún Oore Rẹ̀
1Ẹ ma yìn Oluwa! Ẹ ma yìn, ẹnyin iranṣẹ Oluwa, ẹ ma yìn orukọ Oluwa.
2Ibukún li orukọ Oluwa lati isisiyi lọ ati si i lailai.
3Lati ila-õrun titi o fi de ìwọ rẹ̀ orukọ Oluwa ni ki a yìn.
4Oluwa ga lori gbogbo orilẹ-ède, ogo rẹ̀ si wà lori ọrun.
5Tali o dabi Oluwa Ọlọrun wa, ti o ngbe ibi giga.
6Ẹniti o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ lati wò ohun ti o wà li ọrun ati li aiye!
7O gbé talaka soke lati inu erupẹ wá, o si gbé olupọnju soke lati ori àtan wá;
8Ki o le mu u joko pẹlu awọn ọmọ-alade, ani pẹlu awọn ọmọ-alade awọn enia rẹ̀.
9O mu àgan obinrin gbe inu ile, lati ma ṣe oninu-didùn iya awọn ọmọ. Ẹ ma yìn Oluwa!

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 113: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀