O. Daf 112

112
Ayọ̀ Ẹni Rere
1Ẹ ma yìn Oluwa. Ibukún ni fun ẹniti o bẹ̀ru Oluwa, ti inu rẹ̀ dùn jọjọ sí ofin rẹ̀.
2Iru-ọmọ rẹ̀ yio lagbara li aiye: iran ẹni-diduro-ṣinṣin li a o bukún fun.
3Ọlà ati ọrọ̀ yio wà ni ile rẹ̀: ododo rẹ̀ si duro lailai.
4Fun ẹni-diduro-ṣinṣin ni imọlẹ mọ́ li òkunkun: olore-ọfẹ, o si kún fun ãnu, o si ṣe olododo.
5Enia rere fi oju-rere hàn, a si wínni: imoye ni yio ma fi là ọ̀na iṣẹ rẹ̀.
6Nitoriti a kì yio yi i nipò pada lailai: olododo yio wà ni iranti titi aiye.
7Kì yio bẹ̀ru ihin buburu: aiya rẹ̀ ti mu ọ̀na kan, o gbẹkẹle Oluwa.
8Aiya rẹ̀ ti mulẹ, kì yio bẹ̀ru, titi yio fi ri ifẹ rẹ̀ lori awọn ọta rẹ̀.
9O ti fún ka, o ti fi fun awọn olupọnju; ododo rẹ̀ duro lailai; ọlá li a o fi gbé iwo rẹ̀ ga.
10Awọn enia buburu yio ri i, inu wọn o si bajẹ; yio pa ehin rẹ̀ keke, yio si yọ́ danu: ifẹ awọn enia buburu yio ṣegbe.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 112: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀