O. Daf 111:7-10

O. Daf 111:7-10 YBCV

Otitọ ati idajọ ni iṣẹ ọwọ rẹ̀; gbogbo ofin rẹ̀ li o daniloju. Nwọn duro lai ati lailai, ninu otitọ ati iduro-ṣinṣin li a ṣe wọn. O rán idande si awọn enia rẹ̀: o ti paṣẹ majẹmu rẹ̀ lailai: mimọ́ ati ọ̀wọ li orukọ rẹ̀. Ibẹru Oluwa ni ipilẹṣẹ ọgbọ́n: oye rere ni gbogbo awọn ti npa ofin rẹ̀ mọ́ ni: iyìn rẹ̀ duro lailai.