O. Daf 111:7-10
O. Daf 111:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Otitọ ati idajọ ni iṣẹ ọwọ rẹ̀; gbogbo ofin rẹ̀ li o daniloju. Nwọn duro lai ati lailai, ninu otitọ ati iduro-ṣinṣin li a ṣe wọn. O rán idande si awọn enia rẹ̀: o ti paṣẹ majẹmu rẹ̀ lailai: mimọ́ ati ọ̀wọ li orukọ rẹ̀. Ibẹru Oluwa ni ipilẹṣẹ ọgbọ́n: oye rere ni gbogbo awọn ti npa ofin rẹ̀ mọ́ ni: iyìn rẹ̀ duro lailai.

O. Daf 111:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tọ́, ó sì tọ̀nà, gbogbo ìlànà rẹ̀ sì dájú. Wọ́n wà títí lae ati laelae, ní òtítọ́ ati ìdúróṣinṣin. Ó ṣètò ìràpadà fún àwọn eniyan rẹ̀, ó fi ìdí majẹmu rẹ̀ múlẹ̀ títí lae, mímọ́ ni orúkọ rẹ̀, ó sì lọ́wọ̀. Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, gbogbo àwọn tí ó bá ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, á máa ní ìmọ̀ pípé. Títí lae ni ìyìn rẹ̀.
O. Daf 111:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́; gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú. Wọ́n dúró láé àti láé, ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n. Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀: ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé: Mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀. Ìbẹ̀rù OLúWA ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n: òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀, ìyìn rẹ̀ dúró láé.