O. Daf 108

108
Adura Ìrànlọ́wọ́ láti Borí Ọ̀tá
1OLỌRUN, ọkàn mi ti mura, emi o ma kọrin, emi o si ma fi ogo mi kọrin iyìn.
2Ji, ohun-elo orin mimọ́ ati dùrù: emi tikarami yio si ji ni kutukutu.
3Emi o ma yìn ọ, Oluwa, ninu awọn enia: emi o mã kọrin si ọ ninu awọn orilẹ-ède.
4Nitori ti ãnu rẹ tobi jù ọrun lọ: ati otitọ rẹ titi de awọsanma.
5Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun, lori awọn ọrun: ati ogo rẹ lori gbogbo aiye.
6Ki a le gbà awọn olufẹ rẹ là: fi ọwọ ọtún rẹ ṣe igbala, ki o si da mi lohùn.
7Ọlọrun ti sọ̀rọ ninu ìwa-mimọ́ rẹ̀ pe; Emi o yọ̀, emi o pin Ṣekemu, emi o si wọ̀n afonifoji Sukkotu.
8Ti emi ni Gileadi: ti emi ni Manasse: Efraimu pẹlu li agbara ori mi: Juda li olofin mi:
9Moabu ni ikoko-iwẹsẹ mi; lori Edomu li emi o bọ́ bata mi si; lori Filistia li emi o ho iho-ayọ̀.
10Tani yio mu mi wá sinu ilu olodi ni? tani yio sìn mi lọ si Edomu?
11Iwọ Ọlọrun ha kọ́, ẹniti o ti ṣa wa tì? Ọlọrun, iwọ kì yio si ba awọn ogun wa jade lọ?
12Fun wa ni iranlọwọ ninu ipọnju: nitori asan ni iranlọwọ enia.
13Nipasẹ Ọlọrun li awa o ṣe akin; nitori on ni yio tẹ̀ awọn ọta wa mọlẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 108: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀