O. Daf 109

109
Ìráhùn Ẹni tí Ó Wà ninu Ìṣòro
1MÁṢE pa ẹnu rẹ mọ́, Ọlọrun iyìn mi;
2Nitori ti ẹnu awọn enia buburu, ati ẹnu awọn ẹlẹtan yà silẹ si mi: nwọn ti fi ahọn eke sọ̀rọ si mi.
3Nwọn si fi ọ̀rọ irira yi mi ka kiri; nwọn si mba mi ja li ainidi.
4Nipo ifẹ mi nwọn nṣe ọta mi: ṣugbọn emi ngba adura.
5Nwọn si fi ibi san ire fun mi, ati irira fun ifẹ mi.
6Yan enia buburu tì i: jẹ ki Olufisùn ki o duro li ọwọ ọtún rẹ̀.
7Nigbati a o ṣe idajọ rẹ̀, ki a da a lẹbi: ki adura rẹ̀ ki o di ẹ̀ṣẹ;
8Ki ọjọ rẹ̀ ki o kuru; ki ẹlomiran ki o rọpo iṣẹ rẹ̀.
9Ki awọn ọmọ rẹ̀ ki o di alainibaba, ki aya rẹ̀ ki o di opó.
10Jẹ ki awọn ọmọ rẹ̀ ki o di alarinkiri, ti nṣagbe: ki nwọn ki o ma tọrọ onjẹ jina si ibi ahoro wọn.
11Jẹ ki alọnilọwọ-gbà ki o mu ohun gbogbo ti o ni; ki alejo ki o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ.
12Ki ẹnikẹni ki o má wà lati ṣãnu fun u: má si ṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o si lati ṣe oju rere fun awọn ọmọ rẹ̀ alainibaba.
13Ki a ke ati ọmọ-de-ọmọ rẹ̀ kuro, ati ni iran ti mbọ̀ ki orukọ wọn ki o parẹ.
14Ki a ma ranti ẹ̀ṣẹ awọn baba rẹ̀ lọdọ Oluwa; má si jẹ ki a nù ẹ̀ṣẹ iya rẹ̀ nù.
15Jẹ ki nwọn ki o wà niwaju Oluwa nigbagbogbo, ki o le ke iranti wọn kuro lori ilẹ.
16Nitori ti kò ranti lati ṣãnu, ṣugbọn o ṣe inunibini si ọkunrin talaka ati olupọnju nì, ki o le pa onirobinujẹ-ọkàn.
17Bi o ti fẹ egun, bẹ̃ni ki o de si i: bi inu rẹ̀ kò ti dùn si ire, bẹ̃ni ki o jina si i.
18Bi o ti fi egun wọ ara rẹ li aṣọ bi ẹwu rẹ̀, bẹ̃ni ki o wá si inu rẹ̀ bi omi, ati bi orõro sinu egungun rẹ̀.
19Jẹ ki o ri fun u bi aṣọ ti o bò o lara, ati fun àmure ti o fi gbajá nigbagbogbo.
20Eyi li ère awọn ọta mi lati ọwọ Oluwa wá, ati ti awọn ti nsọ̀rọ ibi si ọkàn mi.
21Ṣugbọn iwọ ṣe fun mi, Ọlọrun Oluwa, nitori orukọ rẹ: nitoriti ãnu rẹ dara, iwọ gbà mi.
22Nitoripe talaka ati olupọnju li emi aiya mi si gbọgbẹ ninu mi.
23Emi nkọja lọ bi ojiji ti o nfà sẹhin, emi ntì soke tì sodò bi eṣú.
24Ẽkun mi di ailera nitori igbawẹ; ẹran-ara mi si gbẹ nitori ailọra.
25Emi di ẹ̀gan fun wọn pẹlu: nigbati nwọn wò mi, nwọn mi ori wọn.
26Ràn mi lọwọ, Oluwa Ọlọrun mi: gbà mi gẹgẹ bi ãnu rẹ.
27Ki nwọn ki o le mọ̀ pe ọwọ rẹ li eyi; pe Iwọ, Oluwa, li o ṣe e.
28Nwọn o ma gegun, ṣugbọn iwọ ma sure: nigbati nwọn ba dide, ki oju ki o tì wọn; ṣugbọn iranṣẹ rẹ yio yọ̀.
29Jẹ ki a fi ìtiju wọ̀ awọn ọta mi li aṣọ, ki nwọn ki o si fi idaru-dapọ̀ wọn bò ara, bi ẹnipe ẹ̀wu.
30Emi o ma fi ẹnu mi yìn Oluwa gidigidi; nitõtọ, emi o ma yìn i lãrin ọ̀pọ enia.
31Nitori ti yio duro li ọwọ ọtún olupọnju, lati gbà a lọwọ awọn ti o nda ọkàn rẹ̀ lẹbi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 109: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀