O. Daf 106:32-48

O. Daf 106:32-48 YBCV

Nwọn bi i ninu pẹlu nibi omi Ijà, bẹ̃li o buru fun Mose nitori wọn: Nitori ti nwọn mu ẹmi rẹ̀ binu, bẹ̃li o fi ẹnu rẹ̀ sọ ọ̀rọ aiyẹ. Nwọn kò run awọn orilẹ-ède na, niti ẹniti Oluwa paṣẹ fun wọn: Ṣugbọn nwọn da ara wọn pọ̀ mọ́ awọn keferi, nwọn si kọ́ iṣẹ wọn. Nwọn si sìn ere wọn: ti o di ikẹkun fun wọn. Nitõtọ nwọn fi ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn rubọ si oriṣa. Nwọn si ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ, ani ẹ̀jẹ awọn ọmọkunrin wọn ati ti awọn ọmọbinrin wọn, ti nwọn fi rubọ si ere Kenaani: ilẹ na si di aimọ́ fun ẹ̀jẹ. Nwọn si fi iṣẹ ara wọn sọ ara wọn di alaimọ́, nwọn si ṣe panṣaga lọ pẹlu iṣẹ wọn. Nitorina ni ibinu Oluwa ṣe ràn si awọn enia rẹ̀, o si korira awọn enia ini rẹ̀. O si fi wọn le awọn keferi lọwọ; awọn ti o korira wọn si ṣe olori wọn. Awọn ọta wọn si ni wọn lara, nwọn si mu wọn sìn labẹ ọwọ wọn. Igba pupọ li o gbà wọn; sibẹ nwọn fi ìmọ wọn mu u binu, a si rẹ̀ wọn silẹ nitori ẹ̀ṣẹ wọn. Ṣugbọn ninu ipọnju o kiyesi wọn, nigbati o gbọ́ ẹkún wọn. O si ranti majẹmu rẹ̀ fun wọn, o si yi ọkàn pada gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀. O si mu wọn ri ãnu loju gbogbo awọn ti o kó wọn ni igbekun. Oluwa Ọlọrun wa, gbà wa, ki o si ṣa wa jọ kuro lãrin awọn keferi, lati ma fi ọpẹ fun orukọ mimọ́ rẹ, ati lati ma ṣogo ninu iyìn rẹ. Olubukún ni Oluwa, Ọlọrun Israeli, lati aiyeraiye: ki gbogbo enia ki o si ma wipe, Amin. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.