O. Daf 106:32-48
O. Daf 106:32-48 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn bi i ninu pẹlu nibi omi Ijà, bẹ̃li o buru fun Mose nitori wọn: Nitori ti nwọn mu ẹmi rẹ̀ binu, bẹ̃li o fi ẹnu rẹ̀ sọ ọ̀rọ aiyẹ. Nwọn kò run awọn orilẹ-ède na, niti ẹniti Oluwa paṣẹ fun wọn: Ṣugbọn nwọn da ara wọn pọ̀ mọ́ awọn keferi, nwọn si kọ́ iṣẹ wọn. Nwọn si sìn ere wọn: ti o di ikẹkun fun wọn. Nitõtọ nwọn fi ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn rubọ si oriṣa. Nwọn si ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ, ani ẹ̀jẹ awọn ọmọkunrin wọn ati ti awọn ọmọbinrin wọn, ti nwọn fi rubọ si ere Kenaani: ilẹ na si di aimọ́ fun ẹ̀jẹ. Nwọn si fi iṣẹ ara wọn sọ ara wọn di alaimọ́, nwọn si ṣe panṣaga lọ pẹlu iṣẹ wọn. Nitorina ni ibinu Oluwa ṣe ràn si awọn enia rẹ̀, o si korira awọn enia ini rẹ̀. O si fi wọn le awọn keferi lọwọ; awọn ti o korira wọn si ṣe olori wọn. Awọn ọta wọn si ni wọn lara, nwọn si mu wọn sìn labẹ ọwọ wọn. Igba pupọ li o gbà wọn; sibẹ nwọn fi ìmọ wọn mu u binu, a si rẹ̀ wọn silẹ nitori ẹ̀ṣẹ wọn. Ṣugbọn ninu ipọnju o kiyesi wọn, nigbati o gbọ́ ẹkún wọn. O si ranti majẹmu rẹ̀ fun wọn, o si yi ọkàn pada gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀. O si mu wọn ri ãnu loju gbogbo awọn ti o kó wọn ni igbekun. Oluwa Ọlọrun wa, gbà wa, ki o si ṣa wa jọ kuro lãrin awọn keferi, lati ma fi ọpẹ fun orukọ mimọ́ rẹ, ati lati ma ṣogo ninu iyìn rẹ. Olubukún ni Oluwa, Ọlọrun Israeli, lati aiyeraiye: ki gbogbo enia ki o si ma wipe, Amin. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.
O. Daf 106:32-48 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n mú OLUWA bínú lẹ́bàá omi Meriba, wọ́n sì fi tiwọn kó bá Mose, nítorí wọ́n mú Mose bínú, ọ̀rọ̀ tí kò yẹ sì ti ẹnu rẹ̀ jáde. Wọn kò pa àwọn eniyan ilẹ̀ náà run, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn, ṣugbọn wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè náà, wọ́n sì kọ́ ìṣe wọn. Wọ́n bọ àwọn oriṣa wọn, èyí sì fa ìpalára fún wọn. Wọ́n fi àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn bọ oriṣa. Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, àní, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkunrin, ati ti àwọn ọmọbinrin wọn, tí wọ́n fi bọ àwọn oriṣa ilẹ̀ Kenaani; wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ sọ ilẹ̀ náà di aláìmọ́. Nítorí náà, wọ́n fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́, wọ́n sì sọ ara wọn di alágbèrè. Nígbà náà ni inú bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀, ó sì kórìíra àwọn ẹni ìní rẹ̀. Ó fi wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lọ́wọ́, títí tí àwọn tí ó kórìíra wọn fi jọba lé wọn lórí. Àwọn ọ̀tá wọn ni wọ́n lára, wọ́n sì fi agbára mú wọn sìn. Ọpọlọpọ ìgbà ni ó gbà wọ́n sílẹ̀, ṣugbọn wọ́n ti pinnu láti máa tàpá sí i, OLUWA sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Sibẹsibẹ, ninu ìnira wọn, ó ṣàánú wọn, nígbà tí ó gbọ́ igbe wọn. Nítorí tiwọn, ó ranti majẹmu tí ó dá, ó sì yí ìpinnu rẹ̀ pada nítorí ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Ó jẹ́ kí àánú wọn ṣe gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn. Gbà wá, OLUWA, Ọlọrun wa, kí o sì kó wa kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, kí á lè máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí á sì lè máa ṣògo ninu ìyìn rẹ. Ẹni ìyìn ni OLUWA, Ọlọrun Israẹli, lae ati laelae. Kí gbogbo eniyan máa wí pé, “Amin!”
O. Daf 106:32-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Níbi omi Meriba, wọ́n bí Ọlọ́run nínú, ohun búburú wá sí orí Mose nítorí wọn. Nítorí tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ẹ̀mí Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ àìdára sì ti ẹnu Mose wá. Wọn kò pa àwọn ènìyàn run gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sọ fún wọn, Ṣùgbọ́n wọ́n dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọn tí ó di ìkẹ́kùn fún wọn. Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọ àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà. Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn. Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀ Wọ́n sì fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́, wọ́n sì ṣe àgbèrè lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn. Nígbà náà ni OLúWA bínú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ ó sì kórìíra àwọn ènìyàn ìní rẹ̀ Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá wọn sì jẹ ọba lórí wọn. Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọn lójú wọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n, Síbẹ̀ wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i wọ́n sì ṣòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n ó kíyèsi wọn nítorí ìṣòro nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn; Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọn Nítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn. Lójú gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn ó mú wọn rí àánú. Gbà wá, OLúWA Ọlọ́run wa, kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrín àwọn kèfèrí, láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ láti máa ṣògo nínú ìyìn rẹ. Olùbùkún ni OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, láti ìrandíran.