Owe 7:1-5

Owe 7:1-5 YBCV

ỌMỌ mi, pa ọ̀rọ mi mọ́, ki o si fi ofin mi ṣe ìṣura pẹlu rẹ. Pa ofin mi mọ́, ki iwọ ki o si yè; ati aṣẹ mi bi ọmọloju rẹ. Dì wọn mọ ika rẹ, kọ wọn si wala aiya rẹ. Wi fun ọgbọ́n pe, Iwọ li arabinrin mi; ki o si pe oye ni ibatan rẹ obinrin: Ki nwọn ki o le pa ọ mọ́ kuro lọwọ obinrin ẹlomiran, lọwọ ajeji ti nfi ọ̀rọ rẹ̀ ṣe ipọnni.