Owe 6:23-26

Owe 6:23-26 YBCV

Nitoripe aṣẹ ni fitila; ofin si ni imọlẹ; ati ibawi ẹkọ́ li ọ̀na ìye: Lati pa ọ mọ́ kuro lọwọ obinrin buburu nì, lọwọ ahọn ìpọnni ajeji obinrin. Máṣe ifẹkufẹ li aiya rẹ si ẹwà rẹ̀; bẹ̃ni ki o má si ṣe jẹ ki on ki o fi ipenpeju rẹ̀ mu ọ. Nitoripe nipasẹ agbere obinrin li enia fi idi oniṣù-akara kan: ṣugbọn aya enia a ma wá iye rẹ̀ daradara.