ÌWÉ ÒWE 6:23-26

ÌWÉ ÒWE 6:23-26 YCE

Nítorí fìtílà ni òfin, ìmọ́lẹ̀ ni ẹ̀kọ́, ìbáwí sì jẹ́ ọ̀nà ìyè, láti pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obinrin burúkú, ati lọ́wọ́ ẹnu alágbèrè obinrin tí ó dùn lọ́rọ̀. Má jẹ́ kí ẹwà rẹ̀ wù ọ́, má sì ṣe jẹ́ kí ó fi ìpéǹpéjú rẹ̀ mú ọ. Owó tí aṣẹ́wó yóo gbà kò ju owó burẹdi lọ, ṣugbọn gbogbo ẹ̀mí rẹ ni alágbèrè yóo fi ọgbọ́n gbà.