Owe 5:15-21

Owe 5:15-21 YBCV

Mu omi lati inu kudu rẹ, ati omi ti nṣàn lati inu kanga rẹ. Jẹ ki isun rẹ ki o ṣàn kakiri, ati awọn odò omi ni ita. Ki nwọn ki o jẹ kiki tirẹ, ki o má ṣe ti awọn ajeji pẹlu rẹ. Jẹ ki orisun rẹ ki o ni ibukun: ki iwọ ki o si ma yọ̀ tiwọ ti aya ìgba-èwe rẹ. Bi abo agbọnrin daradara ati abo igalà, jẹ ki ọmu rẹ̀ ki o ma fi ayọ̀ kún ọ nigbagbogbo; ki o si ma yọ̀ gidigidi ninu ifẹ rẹ̀ nigbakugba. Ọmọ mi, ẽṣe ti iwọ o fi ma yọ̀ ninu ifẹ ajeji obinrin, ti iwọ o fi gbá aiya ajeji obinrin mọra? Nitoripe ọ̀na enia mbẹ niwaju Oluwa, o si nṣiwọ̀n irin wọn gbogbo.