Owe 5:15-21
Owe 5:15-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mu omi lati inu kudu rẹ, ati omi ti nṣàn lati inu kanga rẹ. Jẹ ki isun rẹ ki o ṣàn kakiri, ati awọn odò omi ni ita. Ki nwọn ki o jẹ kiki tirẹ, ki o má ṣe ti awọn ajeji pẹlu rẹ. Jẹ ki orisun rẹ ki o ni ibukun: ki iwọ ki o si ma yọ̀ tiwọ ti aya ìgba-èwe rẹ. Bi abo agbọnrin daradara ati abo igalà, jẹ ki ọmu rẹ̀ ki o ma fi ayọ̀ kún ọ nigbagbogbo; ki o si ma yọ̀ gidigidi ninu ifẹ rẹ̀ nigbakugba. Ọmọ mi, ẽṣe ti iwọ o fi ma yọ̀ ninu ifẹ ajeji obinrin, ti iwọ o fi gbá aiya ajeji obinrin mọra? Nitoripe ọ̀na enia mbẹ niwaju Oluwa, o si nṣiwọ̀n irin wọn gbogbo.
Owe 5:15-21 Yoruba Bible (YCE)
Ìwọ ọkọ, láti inú àmù rẹ ni kí o ti máa mu omi; omi tí ń sun láti inú kànga rẹ ni kí o máa mu. Kò dára kí orísun rẹ máa ṣàn káàkiri, bí omi àgbàrá ní gbogbo òpópónà. Tìrẹ nìkan ṣoṣo ni kí ó jẹ́, má jẹ́ kí àjèjì bá ọ pín ninu rẹ̀. Jẹ́ kí orísun rẹ ní ibukun, kí inú rẹ sì máa dùn sí iyawo tí o fi àárọ̀ gbé. Olólùfẹ́ rẹ tí ó dára bí abo egbin. Jẹ́ kí ẹwù rẹ̀ máa mú inú rẹ dùn nígbà gbogbo, kí ìfẹ́ rẹ̀ máa mú orí rẹ yá nígbàkúùgbà. Kí ló dé, ọmọ mi, tí ìfẹ́ alágbèrè obinrin yóo fi wọ̀ ọ́ lọ́kàn, tí o óo fi máa dìrọ̀ mọ́ obinrin olobinrin? Nítorí OLUWA rí gbogbo ohun tí eniyan ń ṣe, ó sì ń ṣàkíyèsí gbogbo ìrìn rẹ̀.
Owe 5:15-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mu omi láti inú kànga tìrẹ Omi tí ń sàn láti inú kànga rẹ. Ó ha yẹ kí omi ìsun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nà àti odò tí ń sàn lọ sí àárín ọjà? Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan, má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjèjì láéláé. Jẹ́ kí orísun rẹ kí ó ní ìbùkún; kí ìwọ ó sì máa yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ. Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ, Jẹ́ kí ọmú rẹ̀ kí ó máa fi ayọ̀ fún ọ nígbà gbogbo, kí o sì máa yọ̀ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbàkúgbà. Ọmọ mi, èéṣe tí ìwọ ó fi máa yọ̀ nínú ìfẹ́ obìnrin panṣágà, tí ìwọ ó sì fi dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn? Nítorí ọ̀nà ènìyàn kò fi ara sin rárá fún OLúWA Ó sì ń gbé gbogbo ọ̀nà rẹ̀ yẹ̀ wò