Owe 5:1-19

Owe 5:1-19 YBCV

ỌMỌ mi, fiyesi ọgbọ́n mi, ki o si dẹti rẹ si oye mi. Lati ma pa ironu mọ́, ati ki ète rẹ ki o le ma pa ìmọ mọ́. Nitori ti ète awọn ajeji obinrin a ma kán bi oyin, ẹnu rẹ̀ si kunna ju ororo lọ: Ṣugbọn igbẹhin rẹ̀ koro bi idápa, o si mú bi idà olojumeji. Ẹsẹ rẹ̀ nsọkalẹ lọ sinu ikú, ìrin-ẹsẹ rẹ̀ de ipo-okú. Ki iwọ má ba ja ipa-ọ̀na ìye, ipa-ọ̀na rẹ̀ a ma yi sihin yi sọhun, on kò si mọ̀. Njẹ gbọ́ temi nisisiyi, ẹnyin ọmọ, ki ẹnyin ki o máṣe yà kuro li ọ̀rọ ẹnu mi. Takete kuro lọdọ rẹ̀, má si ṣe sunmọ eti ilẹkun ile rẹ̀: Ki iwọ ki o má ba fi ọlá rẹ fun ẹlomiran, ati ọdun rẹ fun ẹni-ìka; Ki a má ba fi ọrọ̀ rẹ fun ajeji enia; ki ère-iṣẹ ọwọ rẹ ki o má ba wà ni ile alejo. Iwọ a si ma kãnu ni ikẹhin rẹ̀, nigbati ẹran-ara ati ara rẹ ba parun. Iwọ a si wipe, emi ha ti korira ẹkọ́ to, ti aiya mi si gàn ìbawi: Ti emi kò gbà ohùn awọn olukọ́ mi gbọ́, tabi ki emi dẹti mi silẹ si awọn ti nkọ́ mi. Emi fẹrẹ wà ninu ibi patapata larin awujọ, ati ni ijọ. Mu omi lati inu kudu rẹ, ati omi ti nṣàn lati inu kanga rẹ. Jẹ ki isun rẹ ki o ṣàn kakiri, ati awọn odò omi ni ita. Ki nwọn ki o jẹ kiki tirẹ, ki o má ṣe ti awọn ajeji pẹlu rẹ. Jẹ ki orisun rẹ ki o ni ibukun: ki iwọ ki o si ma yọ̀ tiwọ ti aya ìgba-èwe rẹ. Bi abo agbọnrin daradara ati abo igalà, jẹ ki ọmu rẹ̀ ki o ma fi ayọ̀ kún ọ nigbagbogbo; ki o si ma yọ̀ gidigidi ninu ifẹ rẹ̀ nigbakugba.