Owe 5:1-19

Owe 5:1-19 Bibeli Mimọ (YBCV)

ỌMỌ mi, fiyesi ọgbọ́n mi, ki o si dẹti rẹ si oye mi. Lati ma pa ironu mọ́, ati ki ète rẹ ki o le ma pa ìmọ mọ́. Nitori ti ète awọn ajeji obinrin a ma kán bi oyin, ẹnu rẹ̀ si kunna ju ororo lọ: Ṣugbọn igbẹhin rẹ̀ koro bi idápa, o si mú bi idà olojumeji. Ẹsẹ rẹ̀ nsọkalẹ lọ sinu ikú, ìrin-ẹsẹ rẹ̀ de ipo-okú. Ki iwọ má ba ja ipa-ọ̀na ìye, ipa-ọ̀na rẹ̀ a ma yi sihin yi sọhun, on kò si mọ̀. Njẹ gbọ́ temi nisisiyi, ẹnyin ọmọ, ki ẹnyin ki o máṣe yà kuro li ọ̀rọ ẹnu mi. Takete kuro lọdọ rẹ̀, má si ṣe sunmọ eti ilẹkun ile rẹ̀: Ki iwọ ki o má ba fi ọlá rẹ fun ẹlomiran, ati ọdun rẹ fun ẹni-ìka; Ki a má ba fi ọrọ̀ rẹ fun ajeji enia; ki ère-iṣẹ ọwọ rẹ ki o má ba wà ni ile alejo. Iwọ a si ma kãnu ni ikẹhin rẹ̀, nigbati ẹran-ara ati ara rẹ ba parun. Iwọ a si wipe, emi ha ti korira ẹkọ́ to, ti aiya mi si gàn ìbawi: Ti emi kò gbà ohùn awọn olukọ́ mi gbọ́, tabi ki emi dẹti mi silẹ si awọn ti nkọ́ mi. Emi fẹrẹ wà ninu ibi patapata larin awujọ, ati ni ijọ. Mu omi lati inu kudu rẹ, ati omi ti nṣàn lati inu kanga rẹ. Jẹ ki isun rẹ ki o ṣàn kakiri, ati awọn odò omi ni ita. Ki nwọn ki o jẹ kiki tirẹ, ki o má ṣe ti awọn ajeji pẹlu rẹ. Jẹ ki orisun rẹ ki o ni ibukun: ki iwọ ki o si ma yọ̀ tiwọ ti aya ìgba-èwe rẹ. Bi abo agbọnrin daradara ati abo igalà, jẹ ki ọmu rẹ̀ ki o ma fi ayọ̀ kún ọ nigbagbogbo; ki o si ma yọ̀ gidigidi ninu ifẹ rẹ̀ nigbakugba.

Owe 5:1-19 Yoruba Bible (YCE)

Ọmọ mi fetí sí ọgbọ́n tí mò ń kọ́ ọ, tẹ́tí rẹ sí òye mi, kí o baà lè ní làákàyè, kí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ lè kún fún ìmọ̀. Nítorí ẹnu alágbèrè obinrin a máa dùn bí oyin, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì tuni lára ju òróró lọ, ṣugbọn níkẹyìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ á korò bí iwọ, ẹnu rẹ̀ á sì mú bí idà olójú meji. Ẹsẹ̀ rẹ̀ ń dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ lọ sinu ikú, ìgbésẹ̀ rẹ̀ sì lọ tààrà sinu ibojì. Ó kọ̀ láti rin ọ̀nà ìyè, ọ̀nà rẹ̀ wọ́, kò sì mọ̀. Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ẹ má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu. Ẹ jìnnà sí alágbèrè obinrin, kí ẹ má tilẹ̀ súnmọ́ ẹnu ọ̀nà rẹ̀, kí ẹ má baà gbé ògo yín fún ẹlòmíràn, kí ẹ sì fi ìgbé ayé yín lé aláìláàánú lọ́wọ́. Kí àjèjì má baà jèrè iṣẹ́ yín, kí làálàá rẹ má sì bọ́ sápò àlejò. Kí o má baà kérora nígbẹ̀yìn ayé rẹ, nígbà tí o bá di ìjẹ fún ẹni ẹlẹ́ni nígbà náà ni o óo wí pé, “Kí ló dé tí mo kórìíra ìtọ́ni, tí ọkàn mi sì kẹ́gàn ìbáwí! N kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn olùkọ́ mi n kò sì gba ti àwọn tí wọn ń tọ́ mi sọ́nà. Èyí ni ó sún mi dé etí bèbè ìparun, láàrin àwùjọ eniyan.” Ìwọ ọkọ, láti inú àmù rẹ ni kí o ti máa mu omi; omi tí ń sun láti inú kànga rẹ ni kí o máa mu. Kò dára kí orísun rẹ máa ṣàn káàkiri, bí omi àgbàrá ní gbogbo òpópónà. Tìrẹ nìkan ṣoṣo ni kí ó jẹ́, má jẹ́ kí àjèjì bá ọ pín ninu rẹ̀. Jẹ́ kí orísun rẹ ní ibukun, kí inú rẹ sì máa dùn sí iyawo tí o fi àárọ̀ gbé. Olólùfẹ́ rẹ tí ó dára bí abo egbin. Jẹ́ kí ẹwù rẹ̀ máa mú inú rẹ dùn nígbà gbogbo, kí ìfẹ́ rẹ̀ máa mú orí rẹ yá nígbàkúùgbà.

Owe 5:1-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọmọ mi, fiyèsí ọgbọ́n mi, kí o sì dẹtí rẹ sí òye mi, Kí ìwọ sì lè ní ìṣọ́ra kí ètè rẹ sì le pa ìmọ̀ mọ́. Nítorí ètè àwọn àjèjì obìnrin a máa sun bi oyin, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kúnná ju òróró lọ. Ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó korò ju òróǹró lọ, ó mú bí idà olójú méjì. Ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikú ìgbésẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú. Kí ìwọ má ba à já ipa ọ̀nà ìyè; ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́. Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ dẹtí sí mi, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe yàgò kúrò nínú ọ̀rọ̀ tí mo sọ. Rìn ní ọ̀nà tí ó jìnnà sí ti rẹ̀, má ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀ Àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo ọlá rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́ àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn. Kí a má ba à fi ọrọ̀ rẹ fún àjèjì ènìyàn, kí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀. Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora, nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó! Ọkàn mi ṣe wá kórìíra ìbáwí! N kò gbọ́rọ̀ sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu, tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́. Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátápátá ní àárín gbogbo àwùjọ ènìyàn.” Mu omi láti inú kànga tìrẹ Omi tí ń sàn láti inú kànga rẹ. Ó ha yẹ kí omi ìsun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nà àti odò tí ń sàn lọ sí àárín ọjà? Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan, má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjèjì láéláé. Jẹ́ kí orísun rẹ kí ó ní ìbùkún; kí ìwọ ó sì máa yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ. Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ, Jẹ́ kí ọmú rẹ̀ kí ó máa fi ayọ̀ fún ọ nígbà gbogbo, kí o sì máa yọ̀ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbàkúgbà.