Owe 30

30
Àwọn Ọ̀rọ̀ tí Aguri sọ
1Ọ̀RỌ Aguri, ọmọ Jake, ọ̀rọ ẹkọ́ ti ọkunrin na ti sọ, fun Itieli, ani fun Itieli ati Ukali.
2Nitõtọ emi ṣiwère jù ẹlomiran lọ, emi kò si ni imoye enia.
3Emi kò tilẹ kọ́ ọgbọ́n, emi kò tilẹ ni ìmọ ohun mimọ́.
4Tali o ti gòke lọ si ọrun, tabi ti o si sọkalẹ wá? tali o kó afẹfẹ jọ li ọwọ rẹ̀? tali o di omi sinu aṣọ; tali o fi gbogbo opin aiye le ilẹ? Orukọ rẹ̀ ti ijẹ, ati orukọ ọmọ rẹ̀ ti ijẹ, bi iwọ ba le mọ̀ ọ?
5Gbogbo ọ̀rọ Oluwa jẹ́ otitọ: on li asà fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le e.
6Iwọ máṣe fi kún ọ̀rọ rẹ̀, ki on má ba ba ọ wi, a si mu ọ li eke.
Àwọn Òwe Mìíràn
7Ohun meji ni mo tọrọ lọdọ rẹ; máṣe fi wọn dù mi ki emi to kú.
8Mu asan ati eke jìna si mi: máṣe fun mi li òṣi, máṣe fun mi li ọrọ̀; fi onjẹ ti o to fun mi bọ mi.
9Ki emi ki o má ba yó jù, ki emi ki o má si sẹ́ ọ, pe ta li Oluwa? tabi ki emi má ba tòṣi, ki emi si jale, ki emi si ṣẹ̀ si orukọ Ọlọrun mi.
10Máṣe fi iranṣẹ sùn oluwa rẹ̀, ki o má ba fi ọ bu, ki iwọ má ba jẹbi.
11Iran kan wà ti nfi baba rẹ̀ bu, ti kò si sure fun iya rẹ̀.
12Iran kan wà, ti o mọ́ li oju ara rẹ̀, ṣugbọn a kò ti iwẹ̀ ẹ nù kuro ninu ẽri rẹ̀.
13Iran kan wà, yẽ, oju rẹ̀ ti gbega to! ipenpeju rẹ̀ si gbé soke.
14Iran kan wà, ehin ẹniti o dabi idà, erigi rẹ̀ dabi ọbẹ, lati jẹ talaka run kuro lori ilẹ, ati awọn alaini kuro ninu awọn enia.
15Eṣúṣu ni ọmọbinrin meji, ti nkigbe pe, Muwá, muwá. Ohun mẹta ni mbẹ ti a kò le tẹ lọrùn lai, ani mẹrin kì iwipe, o to.
16Isa-okú, ati inu àgan; ilẹ ti kì ikún fun omi; ati iná ti kì iwipe, o to.
17Oju ti o sin baba rẹ̀ jẹ, ti o gàn ati gbọ́ ti iya rẹ̀, kanakáná ẹba odò ni yio yọ ọ jade, ọmọ idì a si mu u jẹ.
18Ohun mẹta ni mbẹ ti o ṣe iyanu fun mi, nitõtọ, mẹrin li emi kò mọ̀.
19Ipa idì loju ọrun; ipa ejò lori apata: ipa ọkọ̀ loju okun; ati ìwa ọkunrin pẹlu wundia.
20Bẹ̃ni ìwa agbere obinrin: o jẹun, o si nù ẹnu rẹ̀ nù, o si wipe, emi kò ṣe buburu kan.
21Nitori ohun mẹta, aiye a di rũru, ati labẹ mẹrin ni kò le duro.
22Iranṣẹ, nigbati o jọba; ati aṣiwère, nigbati o yo fun onjẹ;
23Fun obinrin, ti a korira, nigbati a sọ ọ di iyale; ati fun iranṣẹbinrin, nigbati o di arole iya rẹ̀.
24Ohun mẹrin ni mbẹ ti o kerejù lori ilẹ, sibẹ nwọn gbọ́n, nwọn kọ́ni li ẹkọ́.
25Alailagbara enia li ẽra, ṣugbọn nwọn a pese onjẹ wọn silẹ ni ìgba ẹ̀run.
26Alailagbara enia li ehoro, ṣugbọn nwọn a ṣe ìho wọn ni ibi palapala okuta.
27Awọn ẽṣú kò li ọba, sibẹ gbogbo wọn a jade lọ li ọwọ́-ọwọ́;
28Ọmọle fi ọwọ rẹ̀ dì mu, o si wà li ãfin awọn ọba.
29Ohun mẹta ni mbẹ ti nrìn rere, nitõtọ, mẹrin li o dára pupọ ni ìrin rirìn:
30Kiniun ti o lagbara julọ ninu ẹranko, ti kò si pẹhinda fun ẹnikan;
31Ẹṣin ti a dì lẹgbẹ; ati obukọ; ati ọba larin awọn enia rẹ̀.
32Bi iwọ ba ti ṣiwère ni gbigbe ara rẹ soke, tabi bi iwọ ba ti ronú ibi, fi ọwọ rẹ le ẹnu rẹ.
33Nitõtọ, mimì wàra ni imu orí-àmọ́ wá, ati fifun imu ni imu ẹ̀jẹ jade; bẹ̃ni riru ibinu soke ni imu ìja wá.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Owe 30: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀