Owe 3:1-21

Owe 3:1-21 YBCV

ỌMỌ mi, máṣe gbagbe ofin mi; si jẹ ki aiya rẹ ki o pa ofin mi mọ́. Nitori ọjọ gigùn, ati ẹmi gigùn, ati alafia ni nwọn o fi kún u fun ọ. Máṣe jẹ ki ãnu ati otitọ ki o fi ọ silẹ: so wọn mọ ọrùn rẹ; kọ wọn si walã aiya rẹ: Bẹ̃ni iwọ o ri ojurere, ati ọ̀na rere loju Ọlọrun ati enia. Fi gbogbo aiya rẹ gbẹkẹle Oluwa; ma si ṣe tẹ̀ si ìmọ ara rẹ. Mọ̀ ọ ni gbogbo ọ̀na rẹ: on o si ma tọ́ ipa-ọna rẹ. Máṣe ọlọgbọ́n li oju ara rẹ; bẹ̀ru Oluwa, ki o si kuro ninu ibi. On o ṣe ilera si idodo rẹ, ati itura si egungun rẹ. Fi ohun-ini rẹ bọ̀wọ fun Oluwa, ati lati inu gbogbo akọbi ibisi-oko rẹ: Bẹ̃ni aká rẹ yio kún fun ọ̀pọlọpọ, ati agbá rẹ yio si kún fun ọti-waini titun. Ọmọ mi, máṣe kọ̀ ibawi Oluwa; bẹ̃ni ki agara itọ́ni rẹ̀ ki o máṣe dá ọ: Nitoripe ẹniti Oluwa fẹ on ni itọ́, gẹgẹ bi baba ti itọ́ ọmọ ti inu rẹ̀ dùn si. Ibukún ni fun ọkunrin na ti o wá ọgbọ́n ri, ati ọkunrin na ti o gbà oye. Nitori ti òwo rẹ̀ ju òwo fadaka lọ, ère rẹ̀ si jù ti wura daradara lọ. O ṣe iyebiye jù iyùn lọ: ati ohun gbogbo ti iwọ le fẹ, kò si eyi ti a le fi we e. Ọjọ gigùn mbẹ li ọwọ ọtún rẹ̀; ati li ọwọ osì rẹ̀, ọrọ̀ ati ọlá. Ọ̀na rẹ̀, ọ̀na didùn ni, ati gbogbo ipa-ọ̀na rẹ̀, alafia. Igi ìye ni iṣe fun gbogbo awọn ti o dì i mu: ibukún si ni fun ẹniti o dì i mu ṣinṣin. Ọgbọ́n li Oluwa fi fi idi aiye sọlẹ, oye li o si fi pese awọn ọrun. Nipa ìmọ rẹ̀ ni ibú ya soke, ti awọsanma si nsẹ̀ ìri rẹ̀ silẹ. Ọmọ mi, máṣe jẹ ki nwọn ki o lọ kuro li oju rẹ: pa ọgbọ́n ti o yè, ati imoye mọ́

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Owe 3:1-21

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa