Owe 26

26
1BI òjo-didì ni ìgba ẹrun, ati bi òjo ni ìgba ikore, bẹ̃li ọlá kò yẹ fun aṣiwère.
2Bi ẹiyẹ fun iṣikiri, ati alapandẹdẹ fun fifò, bẹ̃ni egún kì yio wá lainidi.
3Lagbà fun ẹṣin, ijanu fun kẹtẹkẹtẹ, ati ọgọ fun ẹhin aṣiwère.
4Máṣe da aṣiwère lohùn gẹgẹ bi wère rẹ̀, ki iwọ pãpa ki o má ba dabi rẹ̀.
5Da aṣiwère lohùn gẹgẹ bi wère rẹ̀, ki on ki o má ba gbọ́n li oju ara rẹ̀.
6Ẹniti o rán iṣẹ nipa ọwọ aṣiwère, o ke ẹsẹ ara rẹ̀ kuro, o si jẹ ara rẹ̀ niya.
7Bi ẹsẹ mejeji ti rọ̀ silẹ lara amukun, bẹ̃li owe li ẹnu awọn aṣiwère.
8Bi ẹniti o fi àpo okuta iyebiye sinu okiti okuta, bẹ̃li ẹniti nfi ọlá fun aṣiwère.
9Bi ẹgún ti igún ọmuti lọwọ, bẹ̃li owe li ẹnu awọn aṣiwère.
10Bi tafatafa ti o mu gbogbo enia gbọgbẹ, bẹ̃ni ẹniti o gbà aṣiwère si iṣẹ, ti o si gba awọn olurekọja si iṣẹ-owo.
11Bi aja ti ipada sinu ẽbì rẹ̀, bẹ̃li aṣiwère itun pada sinu wère rẹ̀.
12Iwọ ri ẹnikan ti o gbọ́n li oju ara rẹ̀? ireti mbẹ fun aṣiwère jù fun u lọ.
13Ọlẹ enia wipe, Kiniun mbẹ li ọ̀na; kiniun mbẹ ni igboro.
14Bi ilẹkun ti iyi lori ìwakun rẹ̀, bẹ̃li ọlẹ lori ẹní rẹ̀.
15Ọlẹ pa ọwọ rẹ̀ mọ́ sinu iṣãsun; kò si le yọ ọ jade pada wá si ẹnu rẹ̀.
16Ọlẹ gbọ́n li oju ara rẹ̀ jù enia meje lọ ti nwọn le fi ọgbọ́n dahùn ọ̀ran.
17Ẹniti nkọja lọ, ti o si dasi ìja ti kì iṣe tirẹ̀, o dabi ẹniti o mu ajá leti.
18Bi asiwin ti nsọ ọ̀kọ, ọfa ati ikú,
19Bẹ̃li ẹniti o tan ẹnikeji rẹ̀ jẹ, ti o si wipe, Iré ha kọ li emi nṣe?
20Nigbati igi tan, ina a kú, bẹ̃ni nigbati olofofo kò si, ìja a da.
21Bi ẹyin ti ri si ẹyin-iná, ati igi si iná; bẹ̃li enia onijà lati da ìja silẹ.
22Ọ̀rọ olofofo dabi adidùn, nwọn a si wọ isalẹ inu lọ.
23Ete jijoni, ati aiya buburu, dabi idarọ fadaka ti a fi bò ìkoko.
24Ẹniti o ba korira, ti o fi ète rẹ̀ ṣe agabagebe, yio si pa ẹ̀tan mọ́ ninu rẹ̀.
25Nigbati o ba sọ̀rọ daradara, máṣe gbà a gbọ́: nitoripe irira meje li o wà li aiya rẹ̀,
26Ẹniti a fi ẹ̀tan bò irira rẹ̀ mọlẹ, ìwa-buburu rẹ̀ li a o fi hàn niwaju gbogbo ijọ:
27Ẹnikẹni ti o ba wà ihò yio ṣubu sinu rẹ̀: ẹniti o ba si nyi okuta, on ni yio pada tọ̀.
28Ahọn eke korira awọn ti a fi njẹniya; ẹnu ipọnni a si ma ṣiṣẹ iparun.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Owe 26: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa