Owe 25

25
Àwọn Òwe Mìíràn tí Solomoni Pa
1WỌNYI pẹlu li owe Solomoni, ti awọn ọkunrin Hesekiah, ọba Judah kọ silẹ.
2Ogo Ọlọrun ni lati pa ọ̀ran mọ́: ṣugbọn ọlá awọn ọba ni lati wadi ọ̀ran.
3Ọrun fun giga, ati ilẹ fun jijin bẹ̃ni a kò le iwadi aiya awọn ọba.
4Mu idarọ kuro ninu fadaka, ohun-elo yio si jade fun alagbẹdẹ fadaka.
5Mu enia buburu kuro niwaju ọba, a o si fi idi itẹ́ rẹ̀ kalẹ ninu ododo.
6Máṣe ṣefefe niwaju ọba, má si ṣe duro ni ipò awọn enia nla.
7Nitoripe, o san ki a wi fun ọ pe, wá soke nihin, jù ki a fà ọ tì sẹhin niwaju ọmọ-alade ti oju rẹ ti ri.
8Máṣe jade lọ kankan lati jà, ki iwọ ki o má ba ṣe alaimọ̀ eyiti iwọ o ṣe li opin rẹ̀, nigbati aladugbo rẹ yio dojutì ọ.
9Ba ẹnikeji rẹ ja ìja rẹ̀; ṣugbọn aṣiri ẹlomiran ni iwọ kò gbọdọ fihàn.
10Ki ẹniti o ba gbọ́ ki o má ba dojuti ọ, ẹ̀gan rẹ kì yio si lọ kuro lai.
11Bi eso igi wura ninu agbọ̀n fadaka, bẹ̃ni ọ̀rọ ti a sọ li akoko rẹ̀.
12Bi oruka wura ati ohun ọṣọ́ wura daradara, bẹ̃li ọlọgbọ́n olubaniwi li eti igbọràn.
13Bi otutu òjo-didì ni ìgba ikore, bẹ̃ni olõtọ ikọ̀ si awọn ti o rán a: nitoriti o tù awọn oluwa rẹ̀ ninu.
14Ẹnikẹni ti o ba ṣefefe ninu ẹ̀bun ẹ̀tan, o dabi awọsanma ati afẹfẹ ti kò ni òjo.
15Ipamọra pipẹ li a fi iyi ọmọ-alade li ọkàn pada, ahọn ti o kunna ni ifọ egungun.
16Bi iwọ ba ri oyin, jẹ eyi ti o to fun ọ, ki o má ba su ọ, iwọ a si bì i.
17Fà ẹṣẹ sẹhin kuro ni ile aladugbo rẹ; ki agara rẹ o má ba da a, on a si korira rẹ.
18Ẹniti o jẹri eke si ẹnikeji rẹ̀, ni olugboro, ati idà, ati ọfà mimu.
19Igbẹkẹle alaiṣõtọ enia ni ìgba ipọnju, o dabi ehin ti o ṣẹ́, ati ẹsẹ̀ ti o yẹ̀ lori ike.
20Bi ẹniti o bọ aṣọ nigba otutu, ati bi ọti-kikan ninu ẽru, bẹ̃li ẹniti nkọrin fun ẹniti inu rẹ̀ bajẹ.
21Bi ebi ba npa ọta rẹ, fun u li onjẹ; bi ongbẹ ba si gbẹ ẹ, fun u li ohun mimu.
22Nitoriti iwọ o kó ẹyin iná jọ si ori rẹ̀, Oluwa yio san fun ọ.
23Afẹfẹ ariwa mu òjo wá, bẹ̃li ahọn isọ̀rọ-ẹni-lẹhin imu oju kikoro wá.
24O san lati joko ni igun òke àja, jù pẹlu onija obinrin lọ ninu ile ajumọgbe.
25Bi omi tutu si ọkàn ti ongbẹ ngbẹ, bẹ̃ni ihin-rere lati ilu okere wá.
26Olododo ti o ṣipo pada niwaju enia buburu, o dabi orisun ti o wú, ati isun-omi ti o bajẹ.
27Kò dara lati mã jẹ oyin pupọ: bẹni kò dara lati mã wa ogo ara ẹni.
28Ẹniti kò le ṣe akoso ara rẹ̀, o dabi ilu ti a wo lulẹ, ti kò si li odi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Owe 25: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa