Owe 25:26-27

Owe 25:26-27 YBCV

Olododo ti o ṣipo pada niwaju enia buburu, o dabi orisun ti o wú, ati isun-omi ti o bajẹ. Kò dara lati mã jẹ oyin pupọ: bẹni kò dara lati mã wa ogo ara ẹni.