Ẹniti o ba fẹ afẹ, yio di talaka: ẹniti o fẹ ọti-waini pẹlu ororo kò le lọrọ̀. Enia buburu ni yio ṣe owo-irapada fun olododo, ati olurekọja ni ipò ẹni diduro-ṣinṣin. O san lati joko li aginju jù pẹlu onija obinrin ati oṣónu lọ. Iṣura fifẹ ati ororo wà ni ibugbe ọlọgbọ́n; ṣugbọn enia aṣiwère ná a bajẹ. Ẹniti o ba tẹle ododo ati ãnu, a ri ìye, ododo, ati ọlá. Ọlọgbọ́n gùn odi ilu awọn alagbara, a si fi idi agbara igbẹkẹle rẹ̀ jalẹ̀. Ẹnikẹni ti o ba pa ẹnu ati ahọn rẹ̀ mọ́, o pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kuro ninu iyọnu. Agberaga ati agidi ẹlẹgàn li orukọ rẹ̀, ẹniti nhùwa ninu ibinu pupọpupọ. Ifẹ ọlẹ pa a; nitoriti, ọwọ rẹ̀ kọ̀ iṣẹ ṣiṣe. O nfi ilara ṣojukokoro ni gbogbo ọjọ: ṣugbọn olododo a ma fi funni kì si idawọduro. Ẹbọ enia buburu, irira ni: melomelo ni nigbati o mu u wá ti on ti ìwakiwa rẹ̀? Ẹlẹri eke yio ṣegbe: ṣugbọn ẹniti o gbọ́, yio ma sọ̀rọ li aiyannu. Enia buburu gbè oju rẹ̀ le: ṣugbọn ẹni iduro-ṣinṣin li o nmu ọ̀na rẹ̀ tọ̀. Kò si ọgbọ́n, kò si imoye, tabi ìgbimọ si Oluwa. A mura ẹṣin silẹ de ọjọ ogun: ṣugbọn iṣẹgun lati ọwọ Oluwa ni.
Kà Owe 21
Feti si Owe 21
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Owe 21:17-31
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò