Owe 21:17-31
Owe 21:17-31 Yoruba Bible (YCE)
Ẹni tí ó fẹ́ràn fàájì yóo di talaka, ẹni tí ó fẹ́ràn ọtí waini ati òróró kò ní lówó lọ́wọ́. Eniyan burúkú ni yóo forí gba ibi tíì bá dé bá olódodo. Alaiṣootọ ni yóo fara gba ìyà tí ó tọ́ sí olóòótọ́ inú. Ó sàn láti máa gbé ààrin aṣálẹ̀, ju kí eniyan máa bá oníjà ati oníkanra obinrin gbé lọ. Ní ilé ọlọ́gbọ́n ni à á tí ń bá nǹkan olówó iyebíye, ṣugbọn òmùgọ̀ a máa ba tirẹ̀ jẹ́. Ẹni tí ń lépa òdodo ati àánú yóo rí ìyè, òdodo, ati iyì. Ọlọ́gbọ́n a máa gba ìlú àwọn alágbára a sì wó ibi ààbò tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé lulẹ̀. Ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ pa ara rẹ̀ mọ́ kúrò ninu ìyọnu. “Oníyẹ̀yẹ́” ni orúkọ ẹni tí ń gbéraga, tí ó sì ń ṣe mo tó báyìí-dà báyìí. Ìrònú ohun tí ọ̀lẹ fẹ́ ni yóo pa á, nítorí ọwọ́ rẹ̀ kọ̀ láti ṣiṣẹ́. Eniyan burúkú a máa ṣe ojúkòkòrò ní gbogbo ìgbà, ṣugbọn olódodo ń fúnni láìdáwọ́dúró. Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú, pàápàá tí ó bá mú un wá pẹlu èrò ibi. Ọ̀rọ̀ ẹlẹ́rìí èké yóo di asán, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹni tí ó fetí sílẹ̀ ni a óo gbàgbọ́. Eniyan burúkú a máa lo ògbójú, ṣugbọn olóòótọ́ máa ń yẹ ọ̀nà ara rẹ̀ wò. Kò sí ọgbọ́n, tabi òye, tabi ìmọ̀, tí ó lè dojú kọ OLUWA kí ó mókè. Eniyan a máa tọ́jú ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun, ṣugbọn OLUWA ló ni ìṣẹ́gun.
Owe 21:17-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́, yóò di tálákà: ẹni tí ó fẹ́ ọtí wáìnì pẹ̀lú òróró kò le lọ́rọ̀. Ènìyàn búburú ni yóò ṣe owó ìràpadà fún olódodo, àti olùrékọjá fún ẹni dídúró ṣinṣin. Ó sàn láti jókòó ní aginjù ju pẹ̀lú oníjà obìnrin àti òṣónú lọ. Ìṣúra iyebíye àti òróró wà ní ibùgbé ọlọ́gbọ́n; ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn n bà á jẹ́. Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè, òdodo, àti ọlá. Ọlọ́gbọ́n gòkè odi ìlú àwọn alágbára, ó sì bi ibi gíga agbára ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ṣubú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹnu àti ahọ́n rẹ̀ mọ́, ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìyọnu. Agbéraga àti alágídí ènìyàn ń gan orúkọ ara rẹ̀ nítorí ó ń hùwà nínú ìwà ìgbéraga rẹ̀, àti nínú ìbínú púpọ̀púpọ̀. Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé, àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò parun láé; nítorí tí ọwọ́ rẹ̀ kọ iṣẹ́ ṣíṣe. Ó ń fi ìlara ṣe ojúkòkòrò ní gbogbo ọjọ́: ṣùgbọ́n olódodo a máa fi fún ni kì í sì í dáwọ́ dúró. Ẹbọ ènìyàn búburú, ìríra ni: mélòó mélòó ni nígbà tí ó mú un wá pẹ̀lú èrò ìwà ibi? Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ẹni tí ó gbọ́, yóò dúró. Ènìyàn búburú mú ojú ara rẹ̀ le: ṣùgbọ́n ẹni ìdúró ṣinṣin ni ó ń mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́. Kò sí ọgbọ́n, kò sí ìmòye, tàbí ìmọ̀ràn tí ó le mókè níwájú OLúWA. A ń múra ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun: ṣùgbọ́n ìṣẹ́gun jẹ́ ti OLúWA.
Owe 21:17-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹniti o ba fẹ afẹ, yio di talaka: ẹniti o fẹ ọti-waini pẹlu ororo kò le lọrọ̀. Enia buburu ni yio ṣe owo-irapada fun olododo, ati olurekọja ni ipò ẹni diduro-ṣinṣin. O san lati joko li aginju jù pẹlu onija obinrin ati oṣónu lọ. Iṣura fifẹ ati ororo wà ni ibugbe ọlọgbọ́n; ṣugbọn enia aṣiwère ná a bajẹ. Ẹniti o ba tẹle ododo ati ãnu, a ri ìye, ododo, ati ọlá. Ọlọgbọ́n gùn odi ilu awọn alagbara, a si fi idi agbara igbẹkẹle rẹ̀ jalẹ̀. Ẹnikẹni ti o ba pa ẹnu ati ahọn rẹ̀ mọ́, o pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kuro ninu iyọnu. Agberaga ati agidi ẹlẹgàn li orukọ rẹ̀, ẹniti nhùwa ninu ibinu pupọpupọ. Ifẹ ọlẹ pa a; nitoriti, ọwọ rẹ̀ kọ̀ iṣẹ ṣiṣe. O nfi ilara ṣojukokoro ni gbogbo ọjọ: ṣugbọn olododo a ma fi funni kì si idawọduro. Ẹbọ enia buburu, irira ni: melomelo ni nigbati o mu u wá ti on ti ìwakiwa rẹ̀? Ẹlẹri eke yio ṣegbe: ṣugbọn ẹniti o gbọ́, yio ma sọ̀rọ li aiyannu. Enia buburu gbè oju rẹ̀ le: ṣugbọn ẹni iduro-ṣinṣin li o nmu ọ̀na rẹ̀ tọ̀. Kò si ọgbọ́n, kò si imoye, tabi ìgbimọ si Oluwa. A mura ẹṣin silẹ de ọjọ ogun: ṣugbọn iṣẹgun lati ọwọ Oluwa ni.