Owe 19:15-29

Owe 19:15-29 YBCV

Imẹlẹ mu ni sun orun fọnfọn; ọkàn ọlẹ li ebi yio si pa. Ẹniti o pa ofin mọ́, o pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́; ṣugbọn ẹniti o ba kẹgàn ọ̀na rẹ̀ yio kú. Ẹniti o ṣãnu fun talaka Oluwa li o win; ati iṣeun rẹ̀, yio san a pada fun u. Nà ọmọ rẹ nigbati ireti wà, má si ṣe gbe ọkàn rẹ le ati pa a. Onibinu nla ni yio jiya; nitoripe bi iwọ ba gbà a, sibẹ iwọ o tun ṣe e. Fetisi ìmọ ki o si gbà ẹkọ́, ki iwọ ki o le gbọ́n ni igbẹhin rẹ. Ete pupọ li o wà li aiya enia; ṣugbọn ìgbimọ Oluwa, eyini ni yio duro. Ẹwà enia ni iṣeun rẹ̀: talaka enia si san jù eleke lọ. Ibẹ̀ru Oluwa tẹ̀ si ìye: ẹniti o ni i yio joko ni itẹlọrun; a kì yio fi ibi bẹ̀ ẹ wọ́. Imẹlẹ enia kì ọwọ rẹ̀ sinu iṣasun, kò si le yọ ọ jade pada wá si ẹnu ara rẹ̀. Lu ẹlẹgàn, òpe yio si kiyesi ara: si ba ẹniti o moye wi, oye ìmọ yio si ye e. Ẹniti o ba nṣìka si baba rẹ̀, ti o si le iya rẹ̀ jade, on li ọmọ ti nṣe itiju, ti o si mu ẹ̀gan wá. Ọmọ mi, dẹkun ati fetisi ẹkọ́ ti imu ni ṣìna kuro ninu ọ̀rọ ìmọ. Ẹlẹri buburu fi idajọ ṣẹsin: ẹnu enia buburu si gbe aiṣedẽde mì. A pèse ọ̀rọ-idajọ fun awọn ẹlẹgàn, ati paṣan fun ẹ̀hin awọn aṣiwère.