Owe 19:15-29

Owe 19:15-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọ̀lẹ ṣíṣe máa ń fa oorun sísùn fọnfọn, ebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra. Ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú. Ẹni tí ó ṣàánú tálákà, OLúWA ní ó yá yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe. Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà; àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú ìparun un rẹ̀. Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀ bí ìwọ bá gbà á là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i. Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́ ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyàn ṣùgbọ́n ìfẹ́ OLúWA ní ó máa ń borí. Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀; ó sàn láti jẹ́ tálákà ju òpùrọ́ lọ. Ìbẹ̀rù OLúWA ń mú ìyè wá: nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láìsí ewu. Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ; kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀. Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n; bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ sí i. Ẹni tí ó ṣìkà sí baba rẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde òun ni ọmọ tí ń ṣe ìtìjú, tí ó sì mú ẹ̀gàn wá. Ọmọ mi, dẹ́kun láti tẹ́tí sí ẹ̀kọ́, tí í mú ni ṣìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀-ìmọ̀. Ẹlẹ́rìí búburú fi ìdájọ́ ṣẹ̀sín, ẹnu ènìyàn búburú sì ń gbé ibi mì. A ti pèsè ìjìyà sílẹ̀ fún ẹlẹ́gàn; àti pàṣán fún ẹ̀yìn àwọn aṣiwèrè.

Owe 19:15-29 Yoruba Bible (YCE)

Ìwà ọ̀lẹ a máa múni sùn fọnfọn, ebi níí sìí pa alápá-má-ṣiṣẹ́. Ẹni tí ó bá pa òfin mọ́, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó pamọ́, ẹni tí ó kọ ọ̀nà Ọlọrun sílẹ̀ yóo kú. Ẹni tí ó ṣe ojurere fún àwọn talaka, OLUWA ni ó ṣe é fún, OLUWA yóo sì san ẹ̀san rẹ̀ fún un. Bá ọmọ rẹ wí nígbà tí ó sì lè gbọ́ ìbáwí, má sì ṣe wá ìparun rẹ̀. Onínúfùfù yóo jìyà inúfùfù rẹ̀, bí o bá gbà á sílẹ̀ lónìí, o níláti tún gbà á sílẹ̀ lọ́la. Gbọ́ ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́, kí o lè rí ọgbọ́n lò lẹ́yìn ọ̀la. Ọpọlọpọ ni èrò tí ó wà lọ́kàn ọmọ eniyan, ṣugbọn ìfẹ́ OLUWA ni àṣẹ. Ohun tí ayé ń fẹ́ lára eniyan ni òtítọ́ inú, talaka sì sàn ju òpùrọ́ lọ. Ìbẹ̀rù OLUWA a máa mú ìyè wá, ẹni tí ó ní i yóo ní ìfọ̀kànbalẹ̀, ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan kò ní ṣẹlẹ̀ sí i. Ọ̀lẹ ti ọwọ́ bọ àwo oúnjẹ, ṣugbọn kò lè bu oúnjẹ sí ẹnu ara rẹ̀. Na pẹ̀gànpẹ̀gàn eniyan, òpè yóo sì kọ́gbọ́n. Bá olóye wí, yóo sì ní ìmọ̀ sí i. Ẹni tí ó bá kó baba rẹ̀ nílé, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde, ọmọ tíí fa ìtìjú ati àbùkù báni ni. Ọmọ mi, bí o bá kọ etí dídi sí ẹ̀kọ́, o óo ṣìnà kúrò ninu ìmọ̀. Ẹlẹ́rìí èké a máa kẹ́gàn ìdájọ́ òtítọ́, eniyan burúkú a máa jẹ ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni jẹun. Ìjìyà ti wà nílẹ̀ fún ẹlẹ́yà, a sì ti tọ́jú pàṣán sílẹ̀ fún ẹ̀yìn òmùgọ̀.