Owe 16:1-4

Owe 16:1-4 YBCV

IMURA aiya, ti enia ni, ṣugbọn lati ọdọ Oluwa ni idadùn ahọn. Gbogbo ọ̀na enia li o mọ́ li oju ara rẹ̀; ṣugbọn Oluwa li o ndiwọ̀n ọkàn. Kó iṣẹ rẹ le Oluwa lọwọ, a o si fi idi ìro-inu rẹ kalẹ. Oluwa ti ṣe ohun gbogbo fun ipinnu rẹ̀: nitõtọ, awọn enia buburu fun ọjọ ibi.