Owe 13:1-25

Owe 13:1-25 YBCV

ỌLỌGBỌ́N ọmọ gbà ẹkọ́ baba rẹ̀; ṣugbọn ẹlẹgàn kò gbọ́ ibawi. Enia yio jẹ rere nipa ère ẹnu rẹ̀; ṣugbọn ifẹ ọkàn awọn olurekọja ni ìwa-agbara. Ẹniti o pa ẹnu rẹ̀ mọ́, o pa ẹmi rẹ̀ mọ́; ṣugbọn ẹniti o ṣi ète rẹ̀ pupọ yio ni iparun. Ọkàn ọlẹ nfẹ, kò si ri nkan; ṣugbọn ọkàn awọn alãpọn li a o mu sanra. Olododo korira ẹ̀tan; ṣugbọn enia buburu mu ni hu ìwa irira on itiju. Ododo pa aduro-ṣinṣin li ọ̀na mọ́; ṣugbọn ìwa-buburu ni imuni ṣubu sinu ẹ̀ṣẹ. Ẹnikan wà ti o nfi ara rẹ̀ ṣe ọlọrọ̀, ṣugbọn kò ni nkan; ẹnikan wà ti o nfi ara rẹ̀ ṣe talaka ṣugbọn o li ọrọ̀ pupọ. Irapada ẹmi enia li ọrọ̀ rẹ̀; ṣugbọn olupọnju kò kiyesi ibawi. Imọlẹ olododo nfi ayọ̀ jó; ṣugbọn fitila enia buburu li a o pa. Nipa kiki igberaga ni ìja ti iwá; ṣugbọn lọdọ awọn ti a fi ìmọ hàn li ọgbọ́n wà. Ọrọ̀ ti a fi ìwa-asan ni yio fàsẹhin; ṣugbọn ẹniti o fi iṣẹ-ọwọ kojọ ni yio ma pọ̀ si i. Ireti pipẹ mu ọkàn ṣàisan; ṣugbọn nigbati ifẹ ba de, igi ìye ni. Ẹnikan ti o ba gàn ọ̀rọ na li a o parun: ṣugbọn ẹniti o bẹ̀ru ofin na, li a o san pada fun. Ofin ọlọgbọ́n li orisun ìye, lati kuro ninu okùn ikú. Oye rere fi ojurere fun ni; ṣugbọn ọ̀na awọn olurekọja ṣoro. Gbogbo amoye enia ni nfi ìmọ ṣiṣẹ; ṣugbọn aṣiwere tan were rẹ̀ kalẹ. Oniṣẹ buburu bọ́ sinu ipọnju; ṣugbọn olõtọ ikọ̀ mu ilera wá. Oṣi ati itiju ni fun ẹniti o kọ̀ ẹkọ́; ṣugbọn ẹniti o ba fetisi ibawi li a o bu ọlá fun. Ifẹ ti a muṣẹ dùnmọ ọkàn; ṣugbọn irira ni fun aṣiwere lati kuro ninu ibi. Ẹniti o mba ọlọgbọ́n rìn yio gbọ́n; ṣugbọn ẹgbẹ awọn aṣiwere ni yio ṣegbe. Ibi nlepa awọn ẹlẹṣẹ̀; ṣugbọn fun awọn olododo, rere li a o ma fi san a. Enia rere fi ogún silẹ fun awọn ọmọ ọmọ rẹ̀; ṣugbọn ọrọ̀ ẹlẹṣẹ̀ li a tò jọ fun olododo, Onjẹ pupọ li o wà ni ilẹ titun awọn talaka; ṣugbọn awọn kan wà ti a nparun nitori aini idajọ; Ẹniti o ba fà ọwọ paṣan sẹhin, o korira ọmọ rẹ̀; ṣugbọn ẹniti o fẹ ẹ a ma tète nà a. Olododo jẹ to itẹrun ọkàn rẹ̀; ṣugbọn inu awọn enia buburu ni yio ṣe alaini.