Owe 13:1-25
Owe 13:1-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌGBỌ́N ọmọ gbà ẹkọ́ baba rẹ̀; ṣugbọn ẹlẹgàn kò gbọ́ ibawi. Enia yio jẹ rere nipa ère ẹnu rẹ̀; ṣugbọn ifẹ ọkàn awọn olurekọja ni ìwa-agbara. Ẹniti o pa ẹnu rẹ̀ mọ́, o pa ẹmi rẹ̀ mọ́; ṣugbọn ẹniti o ṣi ète rẹ̀ pupọ yio ni iparun. Ọkàn ọlẹ nfẹ, kò si ri nkan; ṣugbọn ọkàn awọn alãpọn li a o mu sanra. Olododo korira ẹ̀tan; ṣugbọn enia buburu mu ni hu ìwa irira on itiju. Ododo pa aduro-ṣinṣin li ọ̀na mọ́; ṣugbọn ìwa-buburu ni imuni ṣubu sinu ẹ̀ṣẹ. Ẹnikan wà ti o nfi ara rẹ̀ ṣe ọlọrọ̀, ṣugbọn kò ni nkan; ẹnikan wà ti o nfi ara rẹ̀ ṣe talaka ṣugbọn o li ọrọ̀ pupọ. Irapada ẹmi enia li ọrọ̀ rẹ̀; ṣugbọn olupọnju kò kiyesi ibawi. Imọlẹ olododo nfi ayọ̀ jó; ṣugbọn fitila enia buburu li a o pa. Nipa kiki igberaga ni ìja ti iwá; ṣugbọn lọdọ awọn ti a fi ìmọ hàn li ọgbọ́n wà. Ọrọ̀ ti a fi ìwa-asan ni yio fàsẹhin; ṣugbọn ẹniti o fi iṣẹ-ọwọ kojọ ni yio ma pọ̀ si i. Ireti pipẹ mu ọkàn ṣàisan; ṣugbọn nigbati ifẹ ba de, igi ìye ni. Ẹnikan ti o ba gàn ọ̀rọ na li a o parun: ṣugbọn ẹniti o bẹ̀ru ofin na, li a o san pada fun. Ofin ọlọgbọ́n li orisun ìye, lati kuro ninu okùn ikú. Oye rere fi ojurere fun ni; ṣugbọn ọ̀na awọn olurekọja ṣoro. Gbogbo amoye enia ni nfi ìmọ ṣiṣẹ; ṣugbọn aṣiwere tan were rẹ̀ kalẹ. Oniṣẹ buburu bọ́ sinu ipọnju; ṣugbọn olõtọ ikọ̀ mu ilera wá. Oṣi ati itiju ni fun ẹniti o kọ̀ ẹkọ́; ṣugbọn ẹniti o ba fetisi ibawi li a o bu ọlá fun. Ifẹ ti a muṣẹ dùnmọ ọkàn; ṣugbọn irira ni fun aṣiwere lati kuro ninu ibi. Ẹniti o mba ọlọgbọ́n rìn yio gbọ́n; ṣugbọn ẹgbẹ awọn aṣiwere ni yio ṣegbe. Ibi nlepa awọn ẹlẹṣẹ̀; ṣugbọn fun awọn olododo, rere li a o ma fi san a. Enia rere fi ogún silẹ fun awọn ọmọ ọmọ rẹ̀; ṣugbọn ọrọ̀ ẹlẹṣẹ̀ li a tò jọ fun olododo, Onjẹ pupọ li o wà ni ilẹ titun awọn talaka; ṣugbọn awọn kan wà ti a nparun nitori aini idajọ; Ẹniti o ba fà ọwọ paṣan sẹhin, o korira ọmọ rẹ̀; ṣugbọn ẹniti o fẹ ẹ a ma tète nà a. Olododo jẹ to itẹrun ọkàn rẹ̀; ṣugbọn inu awọn enia buburu ni yio ṣe alaini.
Owe 13:1-25 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀, ṣugbọn ẹlẹ́yà kì í gbọ́ ìbáwí. Eniyan rere a máa rí ire nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀, ṣugbọn ohun tí àwọn ẹlẹ́tàn ń fẹ́ ni ìwà jàgídíjàgan. Ẹni tí ó ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń ṣọ́, ẹni tí ń sọ̀rọ̀ àsọjù yóo parun. Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́ nǹkan, ṣugbọn kò ní rí i, ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ nǹkan. Olóòótọ́ a máa kórìíra èké, ṣugbọn eniyan burúkú a máa hùwà ìtìjú ati àbùkù. Òdodo a máa dáàbò bo ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́, ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ a máa bi eniyan burúkú ṣubú. Ẹnìkan ń ṣe bí ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ kò ní nǹkankan, níbẹ̀ ni ẹlòmíràn ń ṣe bíi talaka, ṣugbọn tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀. Ọlọ́rọ̀ a máa fi ohun ìní rẹ̀ ra ẹ̀mí rẹ̀ pada, ṣugbọn talaka kì í tilẹ̀ gbọ́ ìbáwí. Ìmọ́lẹ̀ olódodo a máa fi ayọ̀ tàn, ṣugbọn fìtílà eniyan burúkú yóo kú. Ìjà ni ìgbéraga máa ń fà, ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn yóo ní ọgbọ́n. Ọrọ̀ tí a fi ìkánjú kójọ kì í pẹ́ dínkù, ṣugbọn ẹni tí ó bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kó ọrọ̀ jọ yóo máa ní àníkún. Bí ìrètí bá pẹ́ jù, a máa kó àárẹ̀ bá ọkàn, ṣugbọn kí á tètè rí ohun tí à ń fẹ́ a máa mú ara yá gágá. Ẹni tí ó kẹ́gàn ìmọ̀ràn yóo parun, ṣugbọn ẹni tí ó bá bẹ̀rù òfin yóo jèrè rẹ̀. Ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè a máa yọni ninu tàkúté ikú. Ẹni tí ó ní òye yóo rí ojurere, ṣugbọn ọ̀nà àwọn tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ìparun wọn. Olóye eniyan a máa fi ìmọ̀ ṣe ohun gbogbo, ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi agọ̀ rẹ̀ yangàn. Iranṣẹ burúkú a máa kó àwọn eniyan sinu wahala, ṣugbọn ikọ̀ tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ a máa mú ìrẹ́pọ̀ wá. Òṣì ati àbùkù ni yóo bá ẹni tí ó kọ ìmọ̀ràn, ṣugbọn ẹni tó bá gba ìbáwí yóo gba iyì. Bí èrò ọkàn ẹni bá ṣẹ, a máa fúnni láyọ̀, ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ kórìíra ati kọ ibi sílẹ̀. Bí eniyan bá ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóo gbọ́n, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń bá òmùgọ̀ kẹ́gbẹ́ yóo ṣìnà. Àjálù kì í dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn olódodo yóo máa rí ire. Eniyan rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń kó ọrọ̀ jọ fún àwọn olóòótọ́. Oko tí talaka dá lè mú ọpọlọpọ oúnjẹ jáde, ṣugbọn àwọn alaiṣootọ níí kó gbogbo rẹ̀ lọ. Ẹni tí kì í bá na ọmọ rẹ̀ kò fẹ́ràn rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóo máa bá a wí. Olódodo a máa jẹ àjẹtẹ́rùn, ṣugbọn eniyan burúkú kì í yó.
Owe 13:1-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́gbọ́n ọmọ gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò gbọ́ ìbáwí. Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ènìyàn ń gbádùn ohun rere ṣùgbọ́n, ìfẹ́ ọkàn aláìṣòótọ́ ní ìwà ipá. Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù gbàù yóò parun. Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkan kan, ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣe ọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn. Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́ Ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú. Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòtítọ́ inú, ṣùgbọ́n ìwà búburú ṣí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ipò. Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkan kan ẹlòmíràn díbọ́n bí i tálákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀. Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀ ṣùgbọ́n tálákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà. Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro, ṣùgbọ́n fìtílà ènìyàn búburú ni a pa kú. Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn. Owó tí a fi ọ̀nà èrú kójọ yóò ṣí lọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀díẹ̀ yóò pọ̀ sí i. Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀ ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè. Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀. Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹ̀kùn ikú. Òye pípé ń mú ni rí ojúrere Ṣùgbọ́n ọ̀nà aláìṣòótọ́ kì í tọ́jọ́. Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀ Ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn. Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdààmú ṣùgbọ́n aṣojú olóòtítọ́ mú ìwòsàn wá. Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di tálákà yóò sì rí ìtìjú, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá. Ìfẹ́ tí a mú ṣẹ dùn mọ́ ọkàn ṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi. Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára. Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo. Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo. Ilẹ̀ ẹ tálákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìre oko wá ṣùgbọ́n àìṣòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ. Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa bá a wí. Olódodo jẹ́wọ́ títí ó fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ikùn ènìyàn búburú.