Filp 3:14-21

Filp 3:14-21 YBCV

Emi nlepa lati de opin ire-ije nì fun ère ìpe giga Ọlọrun ninu Kristi Jesu. Nitorina, ẹ jẹ ki iye awa ti iṣe ẹni pipé ni ero yi: bi ẹnyin bá si ni ero miran ninu ohunkohun, eyi na pẹlu ni Ọlọrun yio fi hàn nyin. Kiki pe, ibiti a ti de na, ẹ jẹ ki a mã rìn li oju ọna kanna, ki a ni ero kanna. Ará, ẹ jumọ ṣe afarawe mi, ẹ si ṣe akiyesi awọn ti nrìn bẹ̃, ani bi ẹ ti ni wa fun apẹrẹ. (Nitori ọ̀pọlọpọ ni nrìn, nipasẹ awọn ẹniti mo ti nwi fun nyin nigbakugba, ani, ti mo si nsọkun bi mo ti nwi fun nyin nisisiyi, pe, ọtá agbelebu Kristi ni nwọn: Igbẹhin ẹniti iṣe iparun, ikùn ẹniti iṣe ọlọrun wọn, ati ogo ẹniti o wà ninu itiju wọn, awọn ẹniti ntọju ohun aiye.) Nitori ilu-ibilẹ wa mbẹ li ọrun: lati ibiti awa pẹlu gbé nfojusọna fun Olugbala, Jesu Kristi Oluwa: Ẹniti yio sọ ara irẹlẹ wa di ọ̀tun ki o le bá ara ogo rẹ̀ mu, gẹgẹ bi iṣẹ-agbara nipasẹ eyiti on le fi tẹ ori ohun gbogbo ba fun ara rẹ̀.