Mò ń làkàkà láti dé òpin iré-ìje mi tíí ṣe èrè ìpè láti òkè wá: ìpè Ọlọrun ninu Kristi Jesu. Nítorí náà, gbogbo àwa tí a ti dàgbà ninu ẹ̀sìn kí á máa ní irú èrò yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá wá ní èrò tí ó yàtọ̀ sí èyí, Ọlọrun yóo fihàn yín. Ṣugbọn bí a ti ń ṣe bọ̀ nípa ìwà ati ìṣe, bẹ́ẹ̀ ni kí á ṣe máa tẹ̀síwájú. Ẹ̀yin ará, gbogbo yín ẹ máa fara wé mi, kí ẹ máa ṣàkíyèsí àwọn tí ń hùwà gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a ti jẹ́ fun yín. Nítorí ọpọlọpọ ń hùwà bí ọ̀tá agbelebu Kristi. Bí mo ti ń sọ fun yín tẹ́lẹ̀ nígbàkúùgbà, bẹ́ẹ̀ ni mo tún ń fi omijé sọ nisinsinyii. Ìparun ni ìgbẹ̀yìn wọn. Ikùn wọn ni ọlọrun wọn. Ohun ìtìjú ni wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga. Afẹ́-ayé ni wọ́n gbé lékàn. Nítorí pé ní tiwa, ọ̀run ni ìlú wa wà, níbi tí a ti ń retí Olùgbàlà, Oluwa Jesu Kristi, ẹni tí yóo tún ara ìrẹ̀lẹ̀ wa ṣe kí ó lè dàbí ara tirẹ̀ tí ó lógo, gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ tí ó fi lè fi ohun gbogbo sí ìkáwọ́ ara rẹ̀.
Kà FILIPI 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: FILIPI 3:14-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò