File 1:4-6

File 1:4-6 YBCV

Emi ndupẹ lọwọ Ọlọrun mi nigbagbogbo, emi nṣe iranti rẹ ninu adura mi, Bi mo ti ngbọ́ ti ifẹ rẹ ati igbagbọ́ ti iwọ ni si Jesu Oluwa, ati si gbogbo awọn enia mimọ́; Ki idapọ igbagbọ́ rẹ le lagbara, ni imọ ohun rere gbogbo ti mbẹ ninu nyin si Kristi.