File 1:4-6
File 1:4-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi ndupẹ lọwọ Ọlọrun mi nigbagbogbo, emi nṣe iranti rẹ ninu adura mi, Bi mo ti ngbọ́ ti ifẹ rẹ ati igbagbọ́ ti iwọ ni si Jesu Oluwa, ati si gbogbo awọn enia mimọ́; Ki idapọ igbagbọ́ rẹ le lagbara, ni imọ ohun rere gbogbo ti mbẹ ninu nyin si Kristi.
File 1:4-6 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà gbogbo tí mo bá ń ranti rẹ ninu adura ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun. Mò ń gbọ́ ìròyìn ìfẹ́ ati igbagbọ tí o ní sí Oluwa Jesu, ati sí gbogbo àwọn onigbagbọ. Adura mi ni pé kí àjọṣepọ̀ tàwa-tìrẹ ninu igbagbọ lè ṣiṣẹ́, láti mú kí òye rẹ pọ̀ sí i nípa gbogbo ohun rere tí a ní ninu Kristi.
File 1:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi, nítorí mo ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jesu Olúwa àti nípa ìfẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn mímọ́. Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ́ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọingbọin, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kristi wá.