Oba Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ní ẹgbẹta ọdún ó dín mẹrinla, kí á tó bí OLUWA wa, (586 B.C.), lẹ́yìn ìṣubú Jerusalẹmu, ni a kọ ìwé kékeré yìí; ṣugbọn kò sí ẹni tí ó mọ àkókò náà ní pàtó. Ní àkókò náà ni Edomu ń yọ ayọ̀ ìṣubú tí ó dé bá Juda tí wọ́n ti jọ jẹ́ ọ̀tá láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn. Wọ́n lo anfaani ìrúkèrúdò tí ó dé bá Juda láti kó ẹrù àwọn ará ìlú ibẹ̀, wọ́n sì tún ran àwọn tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ́wọ́. Ọbadiah sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Edomu yóo jìyà, Israẹli yóo sì ṣẹgun Edomu ati àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá Israẹli.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ìjìyà Edomu 1-14
Ọjọ́ OLUWA 15-21

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Oba Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀