Oba 1

1
1IRAN ti Obadiah. Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi niti Edomu; Awa ti gbọ́ ihìn kan lati ọdọ Oluwa wá, a si ti rán ikọ̀ kan si ãrin awọn keferi, Ẹ dide, ẹ si jẹ ki a dide ogun si i.
OLUWA Yóo Jẹ Edomu Níyà
2Kiyesi i, mo ti sọ iwọ di kekere larin awọn keferi: iwọ di gigàn lọpọlọpọ.
3Irera aiya rẹ ti tàn ọ jẹ, iwọ ti ngbe inu pàlapála apáta, ibugbe ẹniti o ga: ti o nwi li ọkàn rẹ̀ pe, Tani yio mu mi sọkalẹ?
4Bi iwọ tilẹ gbe ara rẹ ga bi idì, ati bi iwọ tilẹ tẹ́ itẹ rẹ sãrin awọn irawọ, lati ibẹ li emi o ti sọ̀ ọ kalẹ, ni Oluwa wi.
5Bi awọn olè tọ̀ ọ wá, bi awọn ọlọṣà li oru, (bawo li a ti ke ọ kuro!) nwọn kì yio ha jale titi nwọn fi ni to? bi awọn aka-eso-ajara wá sọdọ rẹ, nwọn kì yio ha fi ẽṣẹ́ diẹ silẹ?
6Bawo li a ti ṣawari awọn nkan Esau! bawo li a ti wá awọn ohun ikọkọ rẹ̀ jade!
7Gbogbo awọn ẹni imulẹ rẹ ti mu ọ de opin ilẹ rẹ: awọn ti nwọn ti wà li alafia pẹlu rẹ ti tàn ọ jẹ, nwọn si bori rẹ; awọn ti o jẹ onjẹ rẹ ti fi ọgbẹ́ si abẹ rẹ: oye kò si ninu rẹ̀.
8Oluwa wipe, li ọjọ na ki emi o run awọn ọlọgbọn kuro ni Edomu, ati imoye kuro li oke Esau?
9Awọn alagbara rẹ yio si bẹ̀ru, iwọ Temani, nitori ki a le ke olukuluku ti ori oke Esau kuro nitori ipania.
Àwọn Ìdí Tí A Fi Jẹ Edomu Níyà
10Nitori ìwa-ipa si Jakobu arakunrin rẹ itiju yio bò ọ, a o si ke ọ kuro titi lai.
11Ni ọjọ ti iwọ duro li apa keji, ni ọjọ ti awọn alejo kó awọn ogun rẹ̀ ni igbèkun lọ, ti awọn ajeji si wọ inu ibode rẹ̀, ti nwọn si ṣẹ keké lori Jerusalemu, ani iwọ wà bi ọkan ninu wọn.
12Ṣugbọn iwọ kì ba ti ṣiju wo ọjọ arakunrin rẹ ni ọjọ ti on di ajeji; bẹ̃ni iwọ kì ba ti yọ̀ lori awọn ọmọ Juda ni ọjọ iparun wọn; bẹ̃ni iwọ kì ba ti sọ̀rọ irera ni ọjọ wahala.
13Iwọ kì ba ti wọ inu ibode awọn enia mi lọ li ọjọ idãmú wọn; nitotọ, iwọ kì ba ti ṣiju wo ipọnju wọn li ọjọ idãmú wọn, bẹ̃ni iwọ kì ba ti gbe ọwọ́ le ohun ini wọn li ọ̀jọ idãmú wọn.
14Bẹ̃ni iwọ kì ba ti duro ni ikorita lati ké awọn tirẹ̀ ti o ti salà kuro; bẹ̃ni iwọ kì ba ti sé awọn tirẹ̀ ti o kù li ọjọ wahala mọ.
Ọlọrun Yóo Dá Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lẹ́jọ́
15Nitori ọjọ Oluwa kù si dẹdẹ sori gbogbo awọn keferi: bi iwọ ti ṣe, bẹ̃li a o si ṣe si ọ: ẹsan rẹ yio si yipada sori ara rẹ.
16Nitori bi ẹnyin ti mu lori oke mimọ́ mi, bẹ̃ni gbogbo awọn keferi yio ma mu titi, nitõtọ, nwọn o mu, nwọn o si gbemì, nwọn o si wà bi ẹnipe nwọn kò ti si.
Ìṣẹ́gun Israẹli
17Ṣugbọn igbala yio wà lori oke Sioni, yio si jẹ mimọ́, awọn ara ile Jakobu yio si ni ini wọn.
18Ile Jakobu yio si jẹ iná, ati ile Josefu ọwọ́-iná, ati ile Esau fun akeku-koriko, nwọn o si ràn ninu wọn, nwọn o si run wọn; kì yio si sí ẹniti yio kù ni ile Esau: nitori Oluwa ti wi i.
19Awọn ara gusu yio ni oke Esau; awọn ti pẹ̀tẹlẹ yio si ni awọn ara Filistia: nwọn o si ni oko Efraimu, ati oko Samaria: Benjamini yio si ni Gileadi.
20Ati igbèkun ogun yi, ti awọn ọmọ Israeli ti o wà larin awọn ara Kenaani, titi de Sarefati; ati igbèkun Jerusalemu ti o wà ni Sefaradi, yio ni awọn ilu nla gusu.
21Awọn olugbala yio si goke Sioni wá lati ṣe idajọ oke Esau; ijọba na yio si jẹ ti Oluwa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Oba 1: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀