Num 26:52-65

Num 26:52-65 YBCV

OLUWA si sọ fun Mose pe, Fun awọn wọnyi ni ki a pín ilẹ na ni iní gẹgẹ bi iye orukọ. Fun awọn ti o pọ̀ ni ki iwọ ki o fi ilẹ-iní pupọ̀ fun, ati fun awọn ti o kére ni ki iwọ ki o fi diẹ fun: ki a fi ilẹ-iní olukuluku fun u gẹgẹ bi iye awọn ti a kà ninu rẹ̀. Ṣugbọn kèké li a o fi pín ilẹ na: gẹgẹ bi orukọ ẹ̀ya awọn baba wọn ni ki nwọn ki o ní i. Gẹgẹ bi kèké ni ki a pín ilẹ-iní na lãrin awọn pupọ̀ ati diẹ. Wọnyi si li awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Lefi, gẹgẹ bi idile wọn: ti Gerṣoni, idile awọn ọmọ Gerṣoni: ti Kohati, idile awọn ọmọ Kohati: ti Merari, idile awọn ọmọ Merari. Wọnyi ni idile awọn ọmọ Lefi: idile awọn ọmọ Libni, idile awọn ọmọ Hebroni, idile awọn ọmọ Mali, idile awọn ọmọ Muṣi, idile awọn ọmọ Kora. Kohati si bi Amramu. Orukọ aya Amramu a si ma jẹ́ Jokebedi, ọmọbinrin Lefi, ti iya rẹ̀ bi fun Lefi ni Egipti: on si bi Aaroni, ati Mose, ati Miriamu arabinrin wọn fun Amramu. Ati fun Aaroni li a bi Nadabu ati Abihu, Eleasari ati Itamari. Ati Nadabu ati Abihu kú, nigbati nwọn mú iná ajeji wá siwaju OLUWA. Awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mọkanla o le ẹgbẹrun, gbogbo awọn ọkunrin lati ọmọ oṣù kan ati jù bẹ̃ lọ: nitoripe a kò kà wọn kún awọn ọmọ Israeli, nitoriti a kò fi ilẹ-iní fun wọn ninu awọn ọmọ Israeli. Wọnyi li awọn ti a kà lati ọwọ́ Mose ati Eleasari alufa wá, awọn ẹniti o kà awọn ọmọ Israeli ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko. Ṣugbọn ninu wọnyi kò sì ọkunrin kan ninu awọn ti Mose ati Aaroni alufa kà, nigbati nwọn kà awọn ọmọ Israeli li aginjù Sinai. Nitoriti OLUWA ti wi fun wọn pe, Kíku ni nwọn o kú li aginjù. Kò si kù ọkunrin kan ninu wọn, bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, ati Joṣua ọmọ Nuni.