Num 26:52-65

Num 26:52-65 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA sọ fún Mose pé, “Àwọn wọnyi ni kí o pín ilẹ̀ náà fún gẹ́gẹ́ bí iye wọn. Fún àwọn tí ó pọ̀ ní ilẹ̀ pupọ ati àwọn tí ó kéré ní ilẹ̀ kéékèèké. Bí iye eniyan tí ó wà ninu ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ti pọ̀ sí ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún wọn. Gègé ni kí ẹ ṣẹ́, kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún olukuluku ẹ̀yà gẹ́gẹ́ bí iye wọn. Gègé ni kí ẹ ṣẹ́ kí ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ẹ̀yà tí ó pọ̀ ati àwọn ẹ̀yà kéékèèké.” Àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Geriṣoni, ìdílé Kohati ati ìdílé Merari, Àwọn ìdílé tí ó wà ninu ẹ̀yà Lefi nìwọ̀nyí: ìdílé Libini, ìdílé Heburoni, ìdílé Mahili, ìdílé Muṣi ati ìdílé Kora. Kohati ni baba Amramu. Orúkọ aya Amramu ni Jokebedi, ọmọbinrin Lefi tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ijipti. Ó bí Aaroni ati Mose ati Miriamu, arabinrin wọn fún Amramu. Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari ati Itamari. Nadabu ati Abihu kú nígbà tí wọ́n rúbọ sí OLUWA ninu Àgọ́ Àjọ pẹlu iná tí kò mọ́. Gbogbo àwọn ọmọkunrin tí a kà ninu ẹ̀yà Lefi láti ẹni oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé ẹgbẹrun (23,000). Wọn kò kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli nítorí pé wọn kò ní ilẹ̀ ìní ní Israẹli. Gbogbo àwọn tí Mose ati Eleasari kà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá Jọdani létí Jẹriko nìwọ̀nyí. Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó tíì dáyé ninu wọn nígbà tí Mose ati Aaroni alufaa, ka àwọn ọmọ Israẹli ní aṣálẹ̀ Sinai. Nítorí pé OLUWA ti sọ pé gbogbo àwọn ti ìgbà náà ni yóo kú ninu aṣálẹ̀. Kalebu ọmọ Jefune ati Joṣua ọmọ Nuni nìkan ni ó kù lára wọn.

Num 26:52-65 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sọ fún Mose pé, “Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ jẹ́ pínpín fún wọn gẹ́gẹ́ bí ogún wọn gẹ́gẹ́ bí iye orúkọ wọn Fún àwọn ọ̀pọ̀ ni kí ìwọ ó fún ní ogún ìlú púpọ̀ àti fún àwọn tí ó kéré ni kí ìwọ ó fi kékeré fún, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ gba ogún ìbí tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí a kọ. Rí dájú pé ilẹ̀ yìí gbọdọ̀ jẹ́ fífi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọn sì ti pọ̀ tó. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ ẹ̀yà àwọn baba wọn ni kí wọn kí ó ni í. Olúkúlùkù ogún ìní ni a gbọdọ̀ fi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pọ̀ tó láàrín ńlá àti kékeré.” Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Lefi tí a kà nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Gerṣoni, ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni; ti Kohati, ìdílé àwọn ọmọ Kohati; ti Merari, ìdílé àwọn ọmọ Merari. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Lefi; ìdílé àwọn ọmọ Libni, ìdílé àwọn ọmọ Hebroni, ìdílé àwọn ọmọ Mahili, ìdílé àwọn ọmọ Muṣi, ìdílé àwọn ọmọ Kora. (Kohati ni baba Amramu, Orúkọ aya Amramu sì ń jẹ́ Jokebedi, ọmọbìnrin Lefi, tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ejibiti. Òun sì bí Aaroni, Mose, àti Miriamu arábìnrin wọn fún Amramu. Aaroni ni baba Nadabu àti Abihu, Eleasari àti Itamari. Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú, nígbà tí wọ́n rú ẹbọ níwájú OLúWA nígbà tí wọ́n mú iná àjèjì wá.) Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Lefi láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbàá-mọ́kànlá ó-lé-lẹ́gbẹ̀rún (23,000). Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn. Àwọn wọ̀nyí ni Mose àti Eleasari àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Israẹli ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jordani létí Jeriko. Kò sí ẹnìkan nínú àwọn tí Mose àti Aaroni àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Israẹli ní aginjù Sinai. Nítorí OLúWA ti sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kíkú ni wọn yóò kú sí aginjù, kò sì sí ẹnìkankan nínú wọn tí kò kú àfi Kalebu ọmọ Jefunne, àti Joṣua ọmọ Nuni.

Num 26:52-65 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si sọ fun Mose pe, Fun awọn wọnyi ni ki a pín ilẹ na ni iní gẹgẹ bi iye orukọ. Fun awọn ti o pọ̀ ni ki iwọ ki o fi ilẹ-iní pupọ̀ fun, ati fun awọn ti o kére ni ki iwọ ki o fi diẹ fun: ki a fi ilẹ-iní olukuluku fun u gẹgẹ bi iye awọn ti a kà ninu rẹ̀. Ṣugbọn kèké li a o fi pín ilẹ na: gẹgẹ bi orukọ ẹ̀ya awọn baba wọn ni ki nwọn ki o ní i. Gẹgẹ bi kèké ni ki a pín ilẹ-iní na lãrin awọn pupọ̀ ati diẹ. Wọnyi si li awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Lefi, gẹgẹ bi idile wọn: ti Gerṣoni, idile awọn ọmọ Gerṣoni: ti Kohati, idile awọn ọmọ Kohati: ti Merari, idile awọn ọmọ Merari. Wọnyi ni idile awọn ọmọ Lefi: idile awọn ọmọ Libni, idile awọn ọmọ Hebroni, idile awọn ọmọ Mali, idile awọn ọmọ Muṣi, idile awọn ọmọ Kora. Kohati si bi Amramu. Orukọ aya Amramu a si ma jẹ́ Jokebedi, ọmọbinrin Lefi, ti iya rẹ̀ bi fun Lefi ni Egipti: on si bi Aaroni, ati Mose, ati Miriamu arabinrin wọn fun Amramu. Ati fun Aaroni li a bi Nadabu ati Abihu, Eleasari ati Itamari. Ati Nadabu ati Abihu kú, nigbati nwọn mú iná ajeji wá siwaju OLUWA. Awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mọkanla o le ẹgbẹrun, gbogbo awọn ọkunrin lati ọmọ oṣù kan ati jù bẹ̃ lọ: nitoripe a kò kà wọn kún awọn ọmọ Israeli, nitoriti a kò fi ilẹ-iní fun wọn ninu awọn ọmọ Israeli. Wọnyi li awọn ti a kà lati ọwọ́ Mose ati Eleasari alufa wá, awọn ẹniti o kà awọn ọmọ Israeli ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko. Ṣugbọn ninu wọnyi kò sì ọkunrin kan ninu awọn ti Mose ati Aaroni alufa kà, nigbati nwọn kà awọn ọmọ Israeli li aginjù Sinai. Nitoriti OLUWA ti wi fun wọn pe, Kíku ni nwọn o kú li aginjù. Kò si kù ọkunrin kan ninu wọn, bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, ati Joṣua ọmọ Nuni.