NỌMBA 26

26
Ètò Ìkànìyàn Keji
1Lẹ́yìn àjàkálẹ̀ àrùn náà, OLUWA sọ fún Mose ati Eleasari alufaa ọmọ Aaroni pé, 2“Ẹ ka iye àwọn ọmọ Israẹli, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé.” 3Mose ati Eleasari alufaa sì pe àwọn eniyan náà jọ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, lẹ́bàá odò Jọdani, létí Jẹriko, 4wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ka iye àwọn eniyan náà láti ẹni ogún ọdún lọ sókè,” gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.
Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìwọ̀nyí:
5Reubẹni ni àkọ́bí Israẹli. Àwọn ọmọ Reubẹni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Hanoku, ìdílé Palu, 6ìdílé Hesironi, ìdílé Karimi. 7Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Reubẹni jẹ́ ẹgbaa mọkanlelogun ó lé ẹgbẹsan ó dín aadọrin (43,730). 8Palu bí Eliabu, 9Eliabu bí Nemueli, Datani ati Abiramu. Datani ati Abiramu yìí ni wọ́n jẹ́ olókìkí eniyan láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ni wọ́n bá Mose ati Aaroni ṣe gbolohun asọ̀ nígbà tí Kora dìtẹ̀, tí wọ́n tako OLUWA. 10Nígbà náà ni ilẹ̀ lanu, tí ó gbé wọn mì pẹlu Kora, wọ́n sì kú, òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Nígbà náà ni iná jó àwọn aadọta leerugba (250) ọkunrin tí wọn tẹ̀lé Kora, wọ́n sì di ohun ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. 11Ṣugbọn àwọn ọmọ Kora kò kú.
12Àwọn ọmọ Simeoni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Nemueli, ìdílé Jamini, ati ìdílé Jakini; 13ìdílé Sera ati ti Ṣaulu. 14Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Simeoni jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé igba (22,200).
15Àwọn ọmọ Gadi ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Sefoni, ìdílé Hagi, ati ìdílé Ṣuni; 16ìdílé Osini, ati ìdílé Eri; 17ìdílé Arodu ati ìdílé Areli. 18Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Gadi jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (40,500).
19Àwọn ọmọ Juda ni Eri ati Onani. Eri ati Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani. 20Àwọn ọmọ Juda ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Ṣela, ìdílé Peresi, ati ìdílé Sera. 21Àwọn ọmọ Peresi nìwọ̀nyí: ìdílé Hesironi ati ìdílé Hamuli. 22Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Juda jẹ́ ẹgbaa mejidinlogoji ó lé ẹẹdẹgbẹta (76,500).
23Àwọn ọmọ Isakari ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Tola, ìdílé Pua; 24ìdílé Jaṣubu ati ìdílé Ṣimironi. 25Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbaa mejilelọgbọn ó lé ọọdunrun (64,300).
26Àwọn ọmọ Sebuluni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Seredi, ìdílé Eloni ati ìdílé Jaleeli. 27Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Sebuluni jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹẹdẹgbẹta (60,500).
28Àwọn ọmọ Josẹfu ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: Manase ati Efuraimu.
29Àwọn ọmọ Manase ni: ìdílé Makiri, Makiri bí Gileadi. 30Àwọn ọmọ Gileadi nìwọ̀nyí: ìdílé Ieseri, ìdílé Heleki; 31ìdílé Asirieli, ìdílé Ṣekemu; 32ìdílé Ṣemida, ìdílé Heferi. 33Selofehadi ọmọ Heferi kò bí ọmọkunrin kankan, àfi ọmọbinrin. Orúkọ àwọn ọmọbinrin Selofehadi ni Mahila, Noa, Hogila, Milika ati Tirisa. 34Gbogbo àwọn tí a kà ninu ìdílé Manase jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlọgbọn ó lé ẹẹdẹgbẹrin (52,700).
35Àwọn ọmọ Efuraimu ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Ṣutela, ìdílé Bekeri ati ìdílé Tahani. 36Àwọn ọmọ Ṣutela nìwọ̀nyí, ìdílé Erani. 37Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Efuraimu jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (32,500). Àwọn ni ọmọ Josẹfu ní ìdílé-ìdílé.
38Àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Bela, ìdílé Aṣibeli, ìdílé Ahiramu; 39ìdílé Ṣefufamu ati ìdílé Hufamu. 40Àwọn ọmọ Bela nìwọ̀nyí: ìdílé Aridi ati ìdílé Naamani. 41Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Bẹnjamini jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé ẹgbẹjọ (45,600).
42Àwọn ọmọ Dani ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Ṣuhamu. 43Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Dani jẹ́ ẹgbaa mejilelọgbọn ó lé irinwo (64,400).
44Àwọn ọmọ Aṣeri ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Imina, ìdílé Iṣifi ati ìdílé Beria. 45Àwọn ọmọ Beria ni: ìdílé Heberi ati ìdílé Malikieli. 46Orúkọ ọmọ Aṣeri obinrin sì ni Sera. 47Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Aṣeri jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlọgbọn ó lé egbeje (53,400).
48Àwọn ọmọ Nafutali ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Jahiseeli, ìdílé Guni, 49ìdílé Jeseri ati ìdílé Ṣilemu. 50Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Nafutali jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé egbeje (45,400).
51Gbogbo wọn ní àpapọ̀ jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹsan ó dín aadọrin (601,730).#Nọm 1:1-46
52OLUWA sọ fún Mose pé, 53“Àwọn wọnyi ni kí o pín ilẹ̀ náà fún gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 54Fún àwọn tí ó pọ̀ ní ilẹ̀ pupọ ati àwọn tí ó kéré ní ilẹ̀ kéékèèké. Bí iye eniyan tí ó wà ninu ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ti pọ̀ sí ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún wọn. 55Gègé ni kí ẹ ṣẹ́, kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún olukuluku ẹ̀yà gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 56Gègé ni kí ẹ ṣẹ́ kí ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ẹ̀yà tí ó pọ̀ ati àwọn ẹ̀yà kéékèèké.”#Nọm 34:13; Joṣ 14:1-2
57Àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Geriṣoni, ìdílé Kohati ati ìdílé Merari, 58Àwọn ìdílé tí ó wà ninu ẹ̀yà Lefi nìwọ̀nyí: ìdílé Libini, ìdílé Heburoni, ìdílé Mahili, ìdílé Muṣi ati ìdílé Kora. Kohati ni baba Amramu. 59Orúkọ aya Amramu ni Jokebedi, ọmọbinrin Lefi tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ijipti. Ó bí Aaroni ati Mose ati Miriamu, arabinrin wọn fún Amramu. 60Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari ati Itamari.#Nọm 3:2. 61Nadabu ati Abihu kú nígbà tí wọ́n rúbọ sí OLUWA ninu Àgọ́ Àjọ pẹlu iná tí kò mọ́.#Lef 10:1-2; Nọm 3:4. 62Gbogbo àwọn ọmọkunrin tí a kà ninu ẹ̀yà Lefi láti ẹni oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé ẹgbẹrun (23,000). Wọn kò kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli nítorí pé wọn kò ní ilẹ̀ ìní ní Israẹli.
63Gbogbo àwọn tí Mose ati Eleasari kà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá Jọdani létí Jẹriko nìwọ̀nyí. 64Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó tíì dáyé ninu wọn nígbà tí Mose ati Aaroni alufaa, ka àwọn ọmọ Israẹli ní aṣálẹ̀ Sinai. 65Nítorí pé OLUWA ti sọ pé gbogbo àwọn ti ìgbà náà ni yóo kú ninu aṣálẹ̀. Kalebu ọmọ Jefune ati Joṣua ọmọ Nuni nìkan ni ó kù lára wọn.#Nọm 14:26-35.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

NỌMBA 26: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀