NỌMBA 25

25
Àwọn Ọmọ Israẹli ní Peori
1Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí àfonífojì Ṣitimu, àwọn ọkunrin wọn ń bá àwọn ọmọbinrin Moabu tí wọ́n wà níbẹ̀ ṣe àgbèrè. 2Àwọn obinrin wọnyi a sì máa pè wọ́n lọ síbi àsè ìbọ̀rìṣà. Wọn a máa jẹ oúnjẹ wọn, wọn a sì ma bá wọn bọ oriṣa wọn. 3Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe da ara wọn pọ̀ mọ́ oriṣa Baali tí ó wà ní Peori, ibinu OLUWA sì ru sí wọn. 4OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Mú gbogbo àwọn olórí Israẹli, kí o so wọ́n kọ́ sórí igi ninu oòrùn títí tí wọn óo fi kú níwájú OLUWA. Nígbà náà ni n kò tó ni bínú sí àwọn eniyan náà mọ́.” 5Mose sì wí fún àwọn onídàájọ́ Israẹli pé, “Olukuluku yín gbọdọ̀ pa àwọn eniyan rẹ̀ tí ó lọ sin oriṣa Baali tí ó wà ní Peori.”
6Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli mú ọmọbinrin Midiani wọlé lójú Mose ati gbogbo àwọn eniyan, níbi tí wọ́n ti ń sọkún lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ níwájú OLUWA. 7Nígbà tí Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, alufaa, rí i, ó dìde láàrin àwọn eniyan, ó sì mú ọ̀kọ̀ kan, 8ó tọ ọkunrin náà lọ ninu àgọ́ rẹ̀, ó sì fi ọ̀kọ̀ náà gún òun ati obinrin náà ní àgúnyọ. Àjàkálẹ̀ àrùn sì dúró láàrin àwọn ọmọ Israẹli. 9Àwọn tí wọ́n kú ninu àjàkálẹ̀ àrùn náà jẹ́ ẹgbaa mejila (24,000).
10OLUWA sọ fún Mose pé, 11“N kò ní bínú sí Israẹli mọ nítorí ohun tí Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, alufaa, ṣe. Ó kọ̀ láti gba ìbọ̀rìṣà láàyè, nítorí náà ni n kò ṣe ní fi ibinu pa àwọn ọmọ Israẹli run. 12Nítorí náà, sọ fún un pé mo bá a dá majẹmu alaafia. 13Majẹmu náà ni pé mo ti yan òun ati arọmọdọmọ rẹ̀ láti máa ṣe alufaa ní Israẹli títí lae nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọrun rẹ̀, ó sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan Israẹli.”
14Orúkọ ọmọ Israẹli tí ó pa pẹlu ọmọbinrin Midiani ni Simiri, ọmọ Salu, olórí ilé kan ninu ẹ̀yà Simeoni. 15Orúkọ ọmọbinrin Midiani náà ni Kosibi, ọmọ Suri, baálé ilé kan ní ilẹ̀ Midiani.
16OLUWA sọ fún Mose pé, 17“Kọlu àwọn ará Midiani, kí o sì pa wọ́n run 18nítorí ibi tí wọ́n ṣe, ati títàn tí wọ́n tàn yín ní Peori, ati nítorí ọ̀rọ̀ Kosibi, ọmọ baálé kan ní ilẹ̀ Midiani, arabinrin wọn, tí a pa nígbà àjàkálẹ̀ àrùn ti Peori.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

NỌMBA 25: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀