AWỌN ọmọ Israeli si ṣí, nwọn si dó si pẹtẹlẹ̀ Moabu li apa keji Jordani ti o kọjusi Jeriko.
Balaki ọmọ Sippori si ri gbogbo eyiti Israeli ti ṣe si awọn ọmọ Amori.
Moabu si bẹ̀ru awọn enia na gidigidi, nitoriti nwọn pọ̀: aisimi si bá Moabu nitori awọn ọmọ Israeli.
Moabu si wi fun awọn àgba Midiani pe, Nisisiyi li awọn ẹgbẹ yi yio lá ohun gbogbo ti o yi wa ká, bi akọmalu ti ilá koriko igbẹ́. Balaki ọmọ Sippori si jẹ́ ọba awọn ara Moabu ni ìgba na.
O si ránṣẹ si Balaamu ọmọ Beori si Petori, ti o wà lẹba Odò, si ilẹ awọn ọmọ enia rẹ̀, lati pè e wá, wipe, Wò o, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá: si kiyesi i, nwọn bò oju ilẹ, nwọn si joko tì mi:
Njẹ nisisiyi wa, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi; nitoriti nwọn lí agbara jù fun mi; bọya emi o bori, ki awa ki o kọlù wọn, ki emi ki o le lé wọn lọ kuro ni ilẹ yi: nitoriti emi mọ̀ pe ibukún ni fun ẹniti iwọ ba bukún, ifibú si ni ẹniti iwọ ba fibú.
Ati awọn àgba Moabu, ati awọn àgba Midiani dide lọ ti awọn ti ọrẹ ìbere-afọṣẹ li ọwọ́ wọn; nwọn si tọ̀ Balaamu wá, nwọn si sọ ọ̀rọ Balaki fun u.
O si wi fun wọn pe, Ẹ wọ̀ nihin li alẹ yi, emi o si mú ọ̀rọ pada tọ̀ nyin wá, bi OLUWA yio ti sọ fun mi: awọn ijoye Moabu si wọ̀ sọdọ Balaamu.
Ọlọrun si tọ̀ Balaamu wá, o si wipe, Awọn ọkunrin wo ni wọnyi lọdọ rẹ?
Balaamu si wi fun Ọlọrun pe, Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, li o ranṣẹ si mi pe,
Kiyesi i, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá, ti o bò oju ilẹ: wá nisisiyi, fi wọn bú fun mi; bọya emi o le bá wọn jà, emi a si lé wọn lọ.
Ọlọrun si wi fun Balaamu pe, Iwọ kò gbọdọ bá wọn lọ; iwọ kò gbọdọ fi awọn enia na bú: nitoripe ẹni ibukún ni nwọn.
Balaamu si dide li owurọ̀, o si wi fun awọn ijoye Balaki pe, Ẹ ma ba ti nyin lọ si ilẹ nyin: nitoriti OLUWA kọ̀ lati jẹ ki mbá nyin lọ.
Awọn ijoye Moabu si dide, nwọn si tọ̀ Balaki lọ, nwọn si wipe, Balaamu kọ̀ lati bá wa wá.
Balaki si tun rán awọn ijoye si i, ti o si lí ọlá jù wọn lọ.
Nwọn tọ̀ Balaamu wá, nwọn si wi fun u pe, Bayi ni Balaki ọmọ Sippori wi pe, Emi bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki ohun kan ki o di ọ lọwọ lati tọ̀ mi wá:
Nitoripe, emi o sọ ọ di ẹni nla gidigidi, emi o si ṣe ohunkohun ti iwọ wi fun mi: nitorina wá, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi.
Balaamu si dahùn o si wi fun awọn iranṣẹ Balaki pe, Balaki iba fẹ́ fun mi ni ile rẹ̀ ti o kún fun fadaká ati wurà, emi kò le rekọja ọ̀rọ OLUWA Ọlọrun mi, lati ṣe ohun kekere tabi nla.
Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ nyin, ẹ wọ̀ nihin pẹlu li oru yi, ki emi ki o le mọ̀ eyiti OLUWA yio wi fun mi si i.
Ọlọrun si tọ̀ Balaamu wá li oru, o si wi fun u pe, Bi awọn ọkunrin na ba wá pè ọ, dide, bá wọn lọ; ṣugbọn kìki ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ, eyinì ni ki iwọ ki o ṣe.