Num 22:1-20
Num 22:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
AWỌN ọmọ Israeli si ṣí, nwọn si dó si pẹtẹlẹ̀ Moabu li apa keji Jordani ti o kọjusi Jeriko. Balaki ọmọ Sippori si ri gbogbo eyiti Israeli ti ṣe si awọn ọmọ Amori. Moabu si bẹ̀ru awọn enia na gidigidi, nitoriti nwọn pọ̀: aisimi si bá Moabu nitori awọn ọmọ Israeli. Moabu si wi fun awọn àgba Midiani pe, Nisisiyi li awọn ẹgbẹ yi yio lá ohun gbogbo ti o yi wa ká, bi akọmalu ti ilá koriko igbẹ́. Balaki ọmọ Sippori si jẹ́ ọba awọn ara Moabu ni ìgba na. O si ránṣẹ si Balaamu ọmọ Beori si Petori, ti o wà lẹba Odò, si ilẹ awọn ọmọ enia rẹ̀, lati pè e wá, wipe, Wò o, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá: si kiyesi i, nwọn bò oju ilẹ, nwọn si joko tì mi: Njẹ nisisiyi wa, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi; nitoriti nwọn lí agbara jù fun mi; bọya emi o bori, ki awa ki o kọlù wọn, ki emi ki o le lé wọn lọ kuro ni ilẹ yi: nitoriti emi mọ̀ pe ibukún ni fun ẹniti iwọ ba bukún, ifibú si ni ẹniti iwọ ba fibú. Ati awọn àgba Moabu, ati awọn àgba Midiani dide lọ ti awọn ti ọrẹ ìbere-afọṣẹ li ọwọ́ wọn; nwọn si tọ̀ Balaamu wá, nwọn si sọ ọ̀rọ Balaki fun u. O si wi fun wọn pe, Ẹ wọ̀ nihin li alẹ yi, emi o si mú ọ̀rọ pada tọ̀ nyin wá, bi OLUWA yio ti sọ fun mi: awọn ijoye Moabu si wọ̀ sọdọ Balaamu. Ọlọrun si tọ̀ Balaamu wá, o si wipe, Awọn ọkunrin wo ni wọnyi lọdọ rẹ? Balaamu si wi fun Ọlọrun pe, Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, li o ranṣẹ si mi pe, Kiyesi i, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá, ti o bò oju ilẹ: wá nisisiyi, fi wọn bú fun mi; bọya emi o le bá wọn jà, emi a si lé wọn lọ. Ọlọrun si wi fun Balaamu pe, Iwọ kò gbọdọ bá wọn lọ; iwọ kò gbọdọ fi awọn enia na bú: nitoripe ẹni ibukún ni nwọn. Balaamu si dide li owurọ̀, o si wi fun awọn ijoye Balaki pe, Ẹ ma ba ti nyin lọ si ilẹ nyin: nitoriti OLUWA kọ̀ lati jẹ ki mbá nyin lọ. Awọn ijoye Moabu si dide, nwọn si tọ̀ Balaki lọ, nwọn si wipe, Balaamu kọ̀ lati bá wa wá. Balaki si tun rán awọn ijoye si i, ti o si lí ọlá jù wọn lọ. Nwọn tọ̀ Balaamu wá, nwọn si wi fun u pe, Bayi ni Balaki ọmọ Sippori wi pe, Emi bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki ohun kan ki o di ọ lọwọ lati tọ̀ mi wá: Nitoripe, emi o sọ ọ di ẹni nla gidigidi, emi o si ṣe ohunkohun ti iwọ wi fun mi: nitorina wá, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi. Balaamu si dahùn o si wi fun awọn iranṣẹ Balaki pe, Balaki iba fẹ́ fun mi ni ile rẹ̀ ti o kún fun fadaká ati wurà, emi kò le rekọja ọ̀rọ OLUWA Ọlọrun mi, lati ṣe ohun kekere tabi nla. Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ nyin, ẹ wọ̀ nihin pẹlu li oru yi, ki emi ki o le mọ̀ eyiti OLUWA yio wi fun mi si i. Ọlọrun si tọ̀ Balaamu wá li oru, o si wi fun u pe, Bi awọn ọkunrin na ba wá pè ọ, dide, bá wọn lọ; ṣugbọn kìki ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ, eyinì ni ki iwọ ki o ṣe.
Num 22:1-20 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ Israẹli ṣí kúrò, wọ́n lọ pa àgọ́ wọn sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní òdìkejì Jọdani tí ó kọjú sí Jẹriko. Nígbà tí Balaki ọmọ Sipori, ọba Moabu rí gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Israẹli ṣe sí àwọn ará Amori, ẹ̀rù wọn ba òun ati àwọn eniyan rẹ̀ lọpọlọpọ, nítorí pé wọ́n pọ̀. Jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn ará Moabu nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ará Moabu ranṣẹ sí àwọn olórí Midiani pé, “Àwọn eniyan wọnyi yóo run gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká wa bí ìgbà tí mààlúù bá jẹ koríko ninu pápá.” Nítorí náà, Balaki ọmọ Sipori, ọba Moabu ranṣẹ lọ pe Balaamu ọmọ Beori ní Petori lẹ́bàá Odò Yufurate ní ilẹ̀ Amawi pé, “Àwọn eniyan kan jáde ti ilẹ̀ Ijipti wá, wọ́n pàgọ́ sórí ilẹ̀ mi, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ náà. Agbára wọn ju tèmi lọ, nítorí náà, wá bá mi ṣépè lé wọn, bóyá bí mo bá bá wọn jagun, n óo lè ṣẹgun wọn, kí n sì lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ mi. Mo mọ̀ dájú pé ibukun ni fún ẹni tí o bá súre fún; ẹni tí o bá ṣépè fún, olúwarẹ̀ gbé!” Àwọn àgbààgbà Moabu ati Midiani mú owó iṣẹ́ aláfọ̀ṣẹ lọ́wọ́, wọ́n tọ Balaamu wá, wọ́n sì jíṣẹ́ Balaki fún un. Balaamu sọ fún wọn pé, “Ẹ sùn níbí ní alẹ́ yìí, bí ó bá di ọ̀la, n óo sọ ohun tí OLUWA bá sọ fún mi fun yín.” Àwọn àgbààgbà náà sì dúró lọ́dọ̀ Balaamu. Ọlọrun tọ Balaamu wá, ó bi í pé, “Àwọn ọkunrin wo ni wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ yìí?” Balaamu dáhùn pé, “Balaki ọba àwọn ará Moabu ni ó rán wọn sí mi pé, àwọn eniyan kan, tí wọ́n wá láti Ijipti, tẹ̀dó sórí gbogbo ilẹ̀ òun. Ó fẹ́ kí n wá bá òun ṣépè lé wọn, kí ó lè bá wọn jà, kí ó sì lè lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀.” Ọlọrun sọ fún Balaamu pé, “Má bá wọn lọ, má sì ṣépè lé àwọn eniyan náà nítorí ẹni ibukun ni wọ́n.” Nígbà tí Balaamu jí ní òwúrọ̀, ó sọ fún àwọn oníṣẹ́ Balaki pé, “Ẹ máa lọ sí ilẹ̀ yín nítorí OLUWA ti sọ pé n kò gbọdọ̀ ba yín lọ.” Nígbà náà ni wọ́n pada lọ sọ́dọ̀ Balaki, wọn sì sọ fún un wí pé Balaamu kọ̀, kò bá àwọn wá. Balaki tún rán àwọn àgbààgbà mìíràn tí wọ́n pọ̀, tí wọ́n sì ṣe pataki ju àwọn ti iṣaaju lọ sí ọ̀dọ̀ Balaamu. Wọ́n jíṣẹ́ fún un pé Balaki ní, “Mo bẹ̀ ọ́, má jẹ́ kí ohunkohun dí ọ lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ mi. N óo sọ ọ́ di eniyan pataki, ohunkohun tí o bá sọ, n óo ṣe é. Jọ̀wọ́ wá bá mi ṣépè lé àwọn eniyan wọnyi.” Balaamu dá àwọn oníṣẹ́ Balaki lóhùn pé, “Balaki ìbáà fún mi ní ààfin rẹ̀, kí ààfin náà sì kún fún fadaka ati wúrà, n kò ní lòdì sí àṣẹ OLUWA Ọlọrun mi, ninu nǹkan kékeré tabi nǹkan ńlá. Ṣugbọn ẹ sùn níbí ní alẹ́ yìí, kí n lè mọ ohun tí OLUWA yóo tún bá mi sọ.” Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọrun tọ Balaamu wá, ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọkunrin wọnyi wá bẹ̀ ọ́ pé kí o bá wọn lọ, máa bá wọn lọ, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ fún ọ ni o gbọdọ̀ ṣe.”
Num 22:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà àwọn ọmọ Israẹli rin ìrìnàjò lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu wọ́n sì pa ibùdó lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jordani tí ó kọjá lọ sí Jeriko. Nísinsin yìí, Balaki ọmọ Sippori rí gbogbo ohun tí àwọn Israẹli ti ṣe sí àwọn ará Amori, ẹ̀rù sì ba Moabu nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn wà níbẹ̀ nítòótọ́, Moabu kún fún ẹ̀rù nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Moabu sọ fún àwọn àgbàgbà Midiani pé, “Nísinsin yìí ni àwọn wọ̀nyí yóò lá gbogbo ohun tí ó yí wa ká, bí màlúù ṣe ń jẹ koríko tí ó wà nínú oko.” Bẹ́ẹ̀ ni Balaki ọmọ Sippori, tí ó jẹ́ ọba Moabu nígbà náà, rán oníṣẹ́ pé Balaamu ọmọ Beori, tí ó wà ní Petori, ní ẹ̀bá odò Eufurate, ti ilẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ. Balaki sọ pé: “Àwọn ènìyàn kan jáde wá láti Ejibiti; wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ ayé wọ́n sì pa ibùdó súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi. Nísinsin yìí, wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú, nítorí wọ́n ní agbára jù fún mi. Nípa ṣíṣe èyí èmi ó ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ yìí. Nítorí tí mo mọ̀ pé ìbùkún ni fún àwọn tí ìwọ bá bùkún, ìfibú sì ni ẹni tí ìwọ bá fi bú.” Àti àwọn àgbàgbà Moabu àti Midiani sì lọ pẹ̀lú owó àyẹ̀wò lọ́nà wọn, Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Balaamu, wọ́n sọ nǹkan tí Balaki sọ fún wọn. “Ẹ sùn níbí lálẹ́ yìí” Balaamu sọ fún un pé, “Èmi ó padà wá fún un yín ní èsì nǹkan tí OLúWA bá wí fún mi.” Nítorí tí àwọn ìjòyè Moabu dúró sọ́dọ̀ rẹ̀. Ọlọ́run tọ Balaamu wá ó sì wí pé, “Ta ni àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ yìí?” Balaamu sọ fún Ọlọ́run pé, “Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, rán iṣẹ́ yìí sí mi pé: ‘Àwọn ènìyàn kan ti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá tí wọ́n bo ojú ilẹ̀. Nísinsin yìí, wá, kí o wá fi wọ́n bú fún mi. Bóyá Èmi yóò lè bá wọn jà, èmi ó sì lé wọn jáde.’ ” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún Balaamu pé, “Má ṣe bá wọn lọ. Ìwọ kò gbọdọ̀ gé ègún lé àwọn ènìyàn náà lórí, nítorí a ti bùkún wọn.” Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Balaamu dìde ó sì sọ fún àwọn ìjòyè Balaki pé, “Ẹ padà sí orílẹ̀-èdè yín, nítorí tí OLúWA ti kọ̀ láti jẹ́ kí n tẹ̀lé yín.” Nígbà náà àwọn ìjòyè Moabu sì padà tọ Balaki lọ wọ́n sì wí pé, “Balaamu kọ̀ láti tẹ̀lé wa.” Nígbà náà Balaki rán àwọn ìjòyè mìíràn tí wọ́n pọ̀ àwọn tí wọ́n sì níyì ju alákọ́kọ́ lọ. Wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Balaamu wọ́n sì sọ pé: “Èyí ni ohun tí Balaki ọmọ Sippori sọ: Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun kí ó dè ọ́ lọ́nà láti wá sí ọ̀dọ̀ mi, Nítorí pé èmi yóò fún ọ ní ẹ̀bùn dáradára, èmi yóò sì ṣe ohunkóhun tí ìwọ bá sọ. Wá, kí o sì wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú fún mi.” Ṣùgbọ́n Balaamu dá wọn lóhùn pé, “Kódà tí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò ní ṣe ohunkóhun tí ó tóbi tàbí kéré tí ó kọjá òfin OLúWA Ọlọ́run mi. Nísinsin yìí ẹ dúró níbí di ọjọ́ kejì gẹ́gẹ́ bí àwọn tókù ti ṣe nígbà náà èmi yóò mọ ohun tí OLúWA yóò tún sọ fún mi.” Ní alẹ́ ọjọ́ náà Ọlọ́run sì tọ Balaamu wá ó sì sọ wí pé, “Nígbà tí ọkùnrin yìí ti wá pè ọ́, lọ pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ẹnu nǹkan tí mo sọ fún ọ ni kí o ṣe.”