Num 15:1-16

Num 15:1-16 YBCV

OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ ibujoko nyin, ti mo fi fun nyin, Ti ẹnyin o ba si ṣe ẹbọ iná si OLUWA, ẹbọ sisun, tabi ẹbọ, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwá, tabi ninu ajọ nyin lati ṣe õrùn didùn si OLUWA ninu agbo-ẹran, tabi ọwọ́-ẹran: Nigbana ni ki ẹniti nru ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ na si OLUWA ki o mú ẹbọ ohunjijẹ wá, idamẹwa òṣuwọn iyẹfun ti a fi idamẹrin òṣuwọn hini oróro pò: Ati idamẹrin òṣuwọn hini ọti-waini fun ẹbọ ohunmimu ni ki iwọ ki o pèse pẹlu ẹbọ sisun, tabi ẹbọ, fun ọdọ-agutan kan. Tabi fun àgbo kan, ki iwọ ki o pèse ẹbọ ohunjijẹ idamẹwa meji òṣuwọn iyẹfun pẹlu idamẹta òṣuwọn hini oróro: Ati fun ẹbọ ohunmimu, ki iwọ ki o mú idamẹta òṣuwọn hini ọti-waini wá, fun õrùn didùn si OLUWA. Bi iwọ ba si pèse ẹgbọrọ akọmalu kan fun ẹbọ sisun, tabi fun ẹbọ kan, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ alafia si OLUWA: Nigbana ni ki o mu wá pẹlu ẹgbọrọ akọmalu na, ẹbọ ohunjijẹ idamẹwa mẹta òṣuwọn iyẹfun ti a fi àbọ òsuwọn hini oróro pò. Ki iwọ ki o si múwa fun ẹbọ ohunmimu àbọ òṣuwọn hini ọti-waini, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA. Bayi ni ki a ṣe niti akọmalu kan, tabi niti àgbo kan, tabi niti akọ ọdọ-agutan kan, tabi niti ọmọ-ewurẹ kan. Gẹgẹ bi iye ti ẹnyin o pèse, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o ṣe si olukuluku gẹgẹ bi iye wọn. Gbogbo ibilẹ ni ki o ma ṣe nkan wọnyi bayi, nigbati nwọn ba nru ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA. Ati bi alejò kan ba nṣe atipo lọdọ nyin, tabi ẹnikẹni ti o wù ki o ṣe ninu nyin ni iran nyin, ti o si nfẹ́ ru ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA; bi ẹnyin ti ṣe, bẹ̃ni ki on ki o ṣe. Ìlana kan ni ki o wà fun ẹnyin ijọ enia, ati fun alejò ti nṣe atipo lọdọ nyin, ìlana titilai, ni iran-iran nyin: bi ẹnyin ti ri, bẹ̃ni ki alejò ki o si ri niwaju OLUWA. Ofin kan ati ìlana kan ni ki o wà fun nyin, ati fun alejò ti nṣe atipo lọdọ nyin.