OLUWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, bí ẹ bá dé ilẹ̀ tí mo fún yín láti máa gbé, tí ẹ bá mú ninu agbo ẹran yín láti fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA tabi láti fi san ẹ̀jẹ́, tabi láti fi rú ẹbọ àtinúwá, tabi ẹbọ ní ọjọ́ àjọ yín, láti pèsè òórùn dídùn fún OLUWA; ẹni tí ó fẹ́ rúbọ yóo tọ́jú ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi idamẹrin òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò fún ẹbọ ohun jíjẹ; ati idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí fún ẹbọ ohun mímu, pẹlu ẹbọ sísun tabi ẹbọ ọ̀dọ́ aguntan kan. Fún ẹbọ àgbò, yóo wá ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò wá, pẹlu ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini ọtí fún ẹbọ ohun mímu; yóo jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA. Bí ẹ bá mú akọ mààlúù wá fún ọrẹ ẹbọ sísun, tabi fún ìrúbọ láti san ẹ̀jẹ́ tabi fún ẹbọ alaafia sí OLUWA, ẹ óo mú ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdajì òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò wá, pẹlu ìdajì òṣùnwọ̀n hini ọtí waini kan, fún ẹbọ ohun mímu, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun. Yóo jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA. “Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe pẹlu akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan tabi àgbò kọ̀ọ̀kan tabi ọ̀dọ́ àgbò kọ̀ọ̀kan tabi ọmọ aguntan kọ̀ọ̀kan. Ẹ óo mú àwọn nǹkan tí a kà sílẹ̀ wá pẹlu olukuluku ẹran tí ẹ bá fẹ́ fi rúbọ. Nígbà tí àwọn ọmọ onílẹ̀ bá fẹ́ rú ẹbọ sísun, tí ó jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA, wọn óo tẹ̀lé ìlànà yìí. Bí àjèjì kan tí ń gbé ààrin yín, tabi ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrin yín bá fẹ́ rú ẹbọ sísun, tí ó jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo tẹ̀lé ìlànà tí mo fi lélẹ̀ fun yín, ìlànà yìí yóo wà fún ìrandíran yín. Ìlànà kan náà ni yóo wà fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ati àwọn àjèjì tí wọ́n wà láàrin yín. Ìlànà yìí yóo wà títí lae ní ìrandíran yín. Bí ẹ ti rí níwájú OLUWA, bẹ́ẹ̀ náà ni àjèjì tí ó wà láàrin yín rí. Òfin ati ìlànà kan náà ni yóo wà fún ẹ̀yin ati àjèjì tí ń gbé pẹlu yín.”
Kà NỌMBA 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: NỌMBA 15:1-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò