Neh 8:1-8

Neh 8:1-8 YBCV

NIGBANA ni gbogbo awọn enia ko ara wọn jọ bi enia kan si ita ti o wà niwaju ẹnu-bode omi; nwọn si sọ fun Esra akọwe lati mu iwe ofin Mose wá, ti Oluwa ti paṣẹ fun Israeli. Esra alufa si mu ofin na wá iwaju ijọ t'ọkunrin t'obinrin, ati gbogbo awọn ti o le fi oye gbọ́, li ọjọ kini oṣu ekeje. O si kà ninu rẹ̀ niwaju ita ti o wà niwaju ẹnu-bode omi lati owurọ titi di idaji ọjọ, niwaju awọn ọkunrin ati awọn obinrin, ati awọn ti o le ye; gbogbo enia si tẹtisilẹ si iwe ofin. Esra akọwe si duro lori aga iduro sọ̀rọ, ti nwọn ṣe nitori eyi na: lẹba ọdọ rẹ̀ ni Mattitiah si duro, ati Ṣema, ati Anaiah, ati Urijah, ati Hilkiah, ati Maaseiah, li ọwọ ọtun rẹ̀; ati li ọwọ òsi rẹ̀ ni Pedaiah, ati Miṣaeli, ati Malkiah, ati Haṣumu, ati Haṣbadana, Sekariah, ati Meṣullamu. Esra si ṣi iwe na li oju gbogbo enia; (nitori on ga jù gbogbo enia) nigbati o si ṣi i, gbogbo enia dide duro: Esra si fi ibukun fun Oluwa Ọlọrun, ti o tobi. Gbogbo enia si dahun pe, Amin, Amin! pẹlu gbigbe ọwọ wọn soke: nwọn si tẹ̀ ori wọn ba, nwọn si sìn Oluwa ni idojubòlẹ̀. Jeṣua pẹlu ati Bani, ati Ṣerebiah, Jamini, Akkubu, Ṣabbetai, Hodijah, Maaseiah, Kelita, Asariah, Josabadi, Hanani, Pelaiah, ati awọn ọmọ Lefi, mu ki ofin ye awọn enia: awọn enia si duro ni ipò wọn. Bẹ̃ni nwọn kà ninu iwe ofin Ọlọrun ketekete, nwọn tumọ rẹ̀, nwọn si mu ki iwe kikà na ye wọn.