Neh 8:1-8
Neh 8:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni gbogbo awọn enia ko ara wọn jọ bi enia kan si ita ti o wà niwaju ẹnu-bode omi; nwọn si sọ fun Esra akọwe lati mu iwe ofin Mose wá, ti Oluwa ti paṣẹ fun Israeli. Esra alufa si mu ofin na wá iwaju ijọ t'ọkunrin t'obinrin, ati gbogbo awọn ti o le fi oye gbọ́, li ọjọ kini oṣu ekeje. O si kà ninu rẹ̀ niwaju ita ti o wà niwaju ẹnu-bode omi lati owurọ titi di idaji ọjọ, niwaju awọn ọkunrin ati awọn obinrin, ati awọn ti o le ye; gbogbo enia si tẹtisilẹ si iwe ofin. Esra akọwe si duro lori aga iduro sọ̀rọ, ti nwọn ṣe nitori eyi na: lẹba ọdọ rẹ̀ ni Mattitiah si duro, ati Ṣema, ati Anaiah, ati Urijah, ati Hilkiah, ati Maaseiah, li ọwọ ọtun rẹ̀; ati li ọwọ òsi rẹ̀ ni Pedaiah, ati Miṣaeli, ati Malkiah, ati Haṣumu, ati Haṣbadana, Sekariah, ati Meṣullamu. Esra si ṣi iwe na li oju gbogbo enia; (nitori on ga jù gbogbo enia) nigbati o si ṣi i, gbogbo enia dide duro: Esra si fi ibukun fun Oluwa Ọlọrun, ti o tobi. Gbogbo enia si dahun pe, Amin, Amin! pẹlu gbigbe ọwọ wọn soke: nwọn si tẹ̀ ori wọn ba, nwọn si sìn Oluwa ni idojubòlẹ̀. Jeṣua pẹlu ati Bani, ati Ṣerebiah, Jamini, Akkubu, Ṣabbetai, Hodijah, Maaseiah, Kelita, Asariah, Josabadi, Hanani, Pelaiah, ati awọn ọmọ Lefi, mu ki ofin ye awọn enia: awọn enia si duro ni ipò wọn. Bẹ̃ni nwọn kà ninu iwe ofin Ọlọrun ketekete, nwọn tumọ rẹ̀, nwọn si mu ki iwe kikà na ye wọn.

Neh 8:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kinni oṣù náà, gbogbo wọn pátá péjọ pọ̀ sí gbangba ìta níwájú Ẹnubodè Omi, wọ́n sì sọ fún Ẹsira, akọ̀wé, pé kí ó mú ìwé òfin Mose tí OLUWA fún àwọn ọmọ Israẹli wá. Ẹsira, alufaa, gbé ìwé òfin náà jáde siwaju àpéjọ náà, tọkunrin tobinrin, gbogbo àwọn tí wọ́n lè gbọ́ kíkà òfin náà kí ó sì yé wọn ni wọ́n péjọ, ní ọjọ́ kinni oṣù keje. Ẹsira ka ìwé òfin náà sí etígbọ̀ọ́ wọn. Ó kọjú sí ìta gbangba tí ó wà lẹ́bàá Ẹnubode Omi láti àárọ̀ kutukutu títí di ọ̀sán, níwájú tọkunrin tobinrin ati àwọn tí ọ̀rọ̀ òfin náà yé, gbogbo wọn ni wọ́n sì tẹ́tí sí ìwé òfin náà. Ẹsira, akọ̀wé, dúró lórí pèpéle tí wọ́n fi igi kàn fún un, fún ìlò ọjọ́ náà. Matitaya dúró ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Ṣema, Anaaya, Uraya, Hilikaya ati Maaseaya dúró ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún rẹ̀, Pedaaya, Miṣaeli, Malikija, ati Haṣumu, Haṣibadana, Sakaraya ati Meṣulamu sì dúró ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀. Ẹsira ṣí ìwé náà lójú gbogbo eniyan, nítorí pé ó ga ju gbogbo wọn lọ, bí ó ti ṣí ìwé náà gbogbo wọn dìde. Ẹsira yin OLUWA, Ọlọrun, tí ó tóbi, gbogbo àwọn eniyan náà gbé ọwọ́ wọn sókè, wọ́n dáhùn pé “Amin, Amin,” wọ́n tẹríba, wọ́n dojúbolẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA. Àwọn ọmọ Lefi wọnyi: Jeṣua, Bani, Ṣerebaya, Jamini, Akubu, Ṣabetai, Hodaya, Maaseaya, Kelita, Asaraya, Josabadi, Hanani, ati Pelaaya ni wọ́n ń túmọ̀ àwọn òfin náà tí wọ́n sì ń ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn eniyan wọn, gbogbo àwọn eniyan dúró ní ààyè wọn. Wọ́n ka òfin Ọlọrun ninu ìwé náà ketekete, wọ́n túmọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn eniyan, ó sì yé wọn.
Neh 8:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
gbogbo àwọn ènìyàn kó ara wọn jọ bí ẹnìkan ní gbangba ìta níwájú Ibodè Omi. Wọ́n sọ fún Esra akọ̀wé pé kí ó gbé ìwé òfin Mose jáde, èyí tí OLúWA ti pàṣẹ fún Israẹli. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje ni àlùfáà Esra gbé ìwé òfin jáde ní iwájú ìjọ ènìyàn, èyí tí ó jẹ́ àpapọ̀ ọkùnrin àti obìnrin àti gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n le è gbọ́ ọ ní àgbọ́yé. Ó kà á sókè láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán bí ó ti kọjú sí ìta ní iwájú Ibodè Omi ní ojú u gbogbo ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ènìyàn tókù tí òye le è yé tí wọ́n wà níbẹ̀. Gbogbo ènìyàn sì fetísílẹ̀ sí ìwé òfin náà pẹ̀lú ìfarabalẹ̀. Akọ̀wé Esra dìde dúró lórí i pẹpẹ ìdúrólé tí a fi igi kàn fún ètò yìí. Ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ọ̀tún ni Mattitiah, Ṣema, Anaiah, Uriah, Hilkiah àti Maaseiah gbé dúró sí, ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀ ní Pedaiah, Misaeli, Malkiah, Haṣumu, Haṣabadana, Sekariah àti Meṣullamu dúró sí. Esra ṣí ìwé náà, gbogbo ènìyàn sì le rí í nítorí ó dúró níbi tí ó ga ju gbogbo ènìyàn lọ; bí ó sì ti ṣí ìwé náà, gbogbo ènìyàn dìde dúró. Esra yin OLúWA, Ọlọ́run alágbára; gbogbo ènìyàn gbé ọwọ́ wọn sókè, wọ́n sì wí pé “Àmín! Àmín!” Nígbà náà ni wọ́n wólẹ̀ wọ́n sì sin OLúWA ní ìdojúbolẹ̀. Àwọn Lefi—Jeṣua, Bani, Ṣerebiah, Jamini, Akkubu, Ṣabbetai, Hodiah, Maaseiah, Kelita, Asariah, Josabadi, Hanani àti Pelaiah—kọ́ wọn ni òfin náà bí àwọn ènìyàn ṣe wà ní ìdúró síbẹ̀. Wọ́n kà láti inú ìwé òfin Ọlọ́run, wọ́n túmọ̀ rẹ̀, wọ́n ṣe àlàyé kí ohun tí wọ́n kà bá à le yé àwọn ènìyàn yékéyéké.