Neh 5:14-16

Neh 5:14-16 YBCV

Pẹlupẹlu lati akoko ti a ti yàn mi lati jẹ bãlẹ wọn ni ilẹ Juda, lati ogún ọdun titi de ọdun kejilelọgbọn Artasasta ọba, eyinì ni, ọdun mejila, emi ati awọn arakunrin mi kò jẹ onjẹ bãlẹ. Ṣugbọn awọn bãlẹ iṣaju, ti o ti wà, ṣaju mi, di ẹrù wiwo le lori awọn enia, nwọn si ti gbà akara ati ọti-waini, laika ogoji ṣekeli fadaka; pẹlupẹlu awọn ọmọkunrin wọn tilẹ lo agbara lori enia na: ṣugbọn emi kò ṣe bẹ̃ nitori ibẹ̀ru Ọlọrun. Mo si mba iṣẹ odi yi lọ pẹlu, awa kò si rà oko kan: gbogbo awọn ọmọkunrin mi li o si gbajọ sibẹ si iṣẹ na.