Neh 5:14-16
Neh 5:14-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Pẹlupẹlu lati akoko ti a ti yàn mi lati jẹ bãlẹ wọn ni ilẹ Juda, lati ogún ọdun titi de ọdun kejilelọgbọn Artasasta ọba, eyinì ni, ọdun mejila, emi ati awọn arakunrin mi kò jẹ onjẹ bãlẹ. Ṣugbọn awọn bãlẹ iṣaju, ti o ti wà, ṣaju mi, di ẹrù wiwo le lori awọn enia, nwọn si ti gbà akara ati ọti-waini, laika ogoji ṣekeli fadaka; pẹlupẹlu awọn ọmọkunrin wọn tilẹ lo agbara lori enia na: ṣugbọn emi kò ṣe bẹ̃ nitori ibẹ̀ru Ọlọrun. Mo si mba iṣẹ odi yi lọ pẹlu, awa kò si rà oko kan: gbogbo awọn ọmọkunrin mi li o si gbajọ sibẹ si iṣẹ na.
Neh 5:14-16 Yoruba Bible (YCE)
Siwaju sí i, láti ìgbà tí a ti yàn mí sí ipò gomina ní ilẹ̀ Juda, láti ogun ọdún tí Atasasesi ti jọba sí ọdún kejilelọgbọn, èmi ati arakunrin mi kò jẹ oúnjẹ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bíi gomina. Àwọn gomina yòókù tí wọ́n jẹ ṣiwaju mi a máa ni àwọn eniyan lára, wọn a máa gba oúnjẹ mìíràn ati ọtí waini lọ́wọ́ wọn, yàtọ̀ sí ogoji ìwọ̀n Ṣekeli fadaka tí wọn ń gbà. Àwọn iranṣẹ wọn pàápàá a máa ni àwọn eniyan lára. Ṣugbọn, nítèmi, n kò ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé mo bẹ̀rù Ọlọrun. Gbogbo ara ni mo fi bá wọn ṣiṣẹ́ odi mímọ, sibẹ n kò gba ilẹ̀ kankan, gbogbo àwọn iranṣẹ mi náà sì péjú sibẹ láti ṣiṣẹ́.
Neh 5:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Síwájú sí í, láti ogún ọdún ọba Artasasta, nígbà tí a ti yàn mí láti jẹ́ baálẹ̀ wọn ní ilẹ̀ Juda, títí di ọdún kejìlélọ́gbọ̀n ìjọba rẹ̀—ọdún méjìlá, èmi àti àwọn arákùnrin mi kò jẹ oúnjẹ baálẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn baálẹ̀ ìṣáájú—tí ó ti wà ṣáájú mi—gbe àjàgà wúwo lé àwọn ènìyàn lórí yàtọ̀ fún oúnjẹ àti wáìnì wọ́n sì tún gba ogójì ṣékélì fàdákà lọ́wọ́ wọn. Kódà àwọn ìránṣẹ́ wọn tún jẹ gàba lórí wọn. Ṣùgbọ́n èmi kò ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Dípò bẹ́ẹ̀, mo fi ara mi jì fún iṣẹ́ lórí odi yìí. Gbogbo àwọn ènìyàn mi péjọ síbẹ̀ fún iṣẹ́ náà; a kò sì gba ilẹ̀ kankan.