Mo si mọ̀ pe, a kò ti fi ipin awọn ọmọ Lefi fun wọn; awọn ọmọ Lefi ati awọn akọrin, ti nṣe iṣẹ, si ti salọ olukuluku si oko rẹ̀.
Nigbana ni mo si ba awọn ijoye jà, mo si wipe, Ẽṣe ti a fi kọ̀ ile Ọlọrun silẹ? Mo si ko wọn jọ, mo si fi wọn si ipò wọn.
Nigbana ni gbogbo Juda mu idamẹwa ọka ati ọti-waini titun ati ororo wá si ile iṣura.
Mo si yàn olupamọ si ile iṣura, Ṣelemiah alufa ati Sadoku akọwẹ, ati ninu awọn ọmọ Lefi, Pedaiah: ati lọwọkọwọ wọn ni Hanani ọmọ Sakkuri, ọmọ Mattaniah: nitoriti a kà wọn si olõtọ, iṣẹ́ wọn si ni lati ma pin fun awọn arakunrin wọn.
Ranti mi, Ọlọrun mi, nitori eyi, ki o má si nu iṣẹ rere ti mo ti ṣe fun ile Ọlọrun mi, nu kuro, ati fun akiyesi rẹ̀.
Li ọjọ wọnni ni mo ri awọn kan ti nfunti ni Juda li ọjọ isimi, awọn ti nmu iti ọka wale, ti ndi ẹrù rù kẹtẹkẹtẹ; ti ọti-waini, pẹlu eso àjara, ati eso ọ̀pọtọ, ati gbogbo oniruru ẹrù ti nwọn nmu wá si Jerusalemu li ọjọ isimi: mo si jẹri gbè wọn li ọjọ ti nwọn ntà ohun jijẹ.
Awọn ara Tire ngbe ibẹ pẹlu, ti nwọn mu ẹja, ati oniruru ohun èlo wá, nwọn si ntà li ọjọ isimi fun awọn ọmọ Juda, ati ni Jerusalemu.
Nigbana ni mo ba awọn ijoye Juda jà, mo si wi fun wọn pe, ohun buburu kili ẹnyin nṣe yi, ti ẹ si mba ọjọ isimi jẹ.
Bayi ha kọ́ awọn baba nyin ṣe, Ọlọrun kò ha mu ki gbogbo ibi yi wá sori wa, ati sori ilu yi? ṣugbọn ẹnyin mu ibinu ti o pọ̀ju wá sori Israeli nipa biba ọjọ isimi jẹ.
O si ṣe, nigbati ẹnu-bode Jerusalemu bẹ̀rẹ si iṣu okunkun ṣaju ọjọ isimi, mo paṣẹ pe, ki a tì ilẹkun, ki ẹnikẹni má ṣi i titi di ẹhin ọjọ isimi, ninu awọn ọmọkunrin mi ni mo fi si ẹnu-bode, ki a má ba mu ẹrù wọle wá li ọjọ isimi.
Bẹ̃ni awọn oniṣòwo ati awọn ti ntà oniruru nkan sùn lẹhin odi Jerusalemu li ẹrinkan tabi ẹrinmeji.
Nigbana ni mo jẹri gbè wọn, mo si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi sùn lẹhin odi, bi ẹnyin ba tun ṣe bẹ̃, emi o fọwọ bà nyin. Lati àkoko na lọ ni nwọn kò si wá lọjọ isimi mọ.
Mo si paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, ki nwọn ya ara wọn si mimọ, ki nwọn si wa ṣọ ẹnu-bode lati pa ọjọ isimi mọ. Ranti mi Ọlọrun mi nitori eyi pẹlu, ki o si da mi si gẹgẹ bi ọ̀pọ ãnu rẹ.
Pẹlupẹlu li ọjọ wọnni, mo ri ara Juda ti mba obinrin awọn ara Aṣdodi, Ammoni, ati ti Moabu gbe:
Awọn ọmọ wọn si nsọ apakan ède Aṣdodi, nwọn kò si le sọ̀rọ li ède awọn ara Juda, ṣugbọn gẹgẹ bi ède olukuluku.
Mo si ba wọn jà, mo gàn wọn, mo lù ninu wọn, mo tu irun wọn, mo mu wọn fi Ọlọrun bura pe, Ẹnyin kì yio fi ọmọbinrin nyin fun ọmọkunrin nwọn, tabi ọmọbinrin nwọn fun ọmọkunrin nyin tabi fun ara nyin.
Solomoni ọba Israeli kò ha dẹṣẹ nipa nkan wọnyi? Bẹ̃ni li ãrin orilẹ-ède pupọ, kò si ọba kan bi on ti Ọlọrun rẹ̀ fẹràn; Ọlọrun si fi jẹ ọba li ori gbogbo Israeli, bẹ̃ni on li awọn àjeji obinrin mu ki o ṣẹ̀.
Njẹ ki awa ha gbọ́ ti nyin, lati ṣe gbogbo buburu nla yi, lati ṣẹ̀ si Ọlọrun sa, ni gbigbe awọn àjeji obinrin ni iyawo?
Ati ọkan ninu awọn ọmọ Jehoiada, ọmọ Eliaṣibu olori alufa, jẹ ana Sanballati, ara Horoni, nitori na mo le e kuro lọdọ mi.
Ranti wọn, Ọlọrun mi, nitoriti nwọn ti ba oyè alufa jẹ, pẹlu majẹmu oyè-alufa, ati ti awọn ọmọ Lefi.
Bayi ni mo wẹ̀ wọn nù kuro ninu gbogbo awọn alejo, mo si yan ẹ̀ṣọ awọn alufa, ati ti awọn ọmọ Lefi, olukuluku ninu iṣẹ tirẹ̀.
Ati fun ẹ̀bun igi li àkoko ti a yàn, ati fun akọso. Ranti mi, Ọlọrun mi, fun rere.